Èmi Paulu, ẹrú Ọlọrun, ati aposteli Jesu Kristi, ni mò ń kọ ìwé yìí.
Oluwa yàn mí láti jẹ́ kí àwọn àyànfẹ́ Ọlọrun lè ní igbagbọ ati ìmọ̀ òtítọ́ ti ẹ̀sìn, ati ìrètí ìyè ainipẹkun, tí Ọlọrun tí kì í purọ́ ti ṣèlérí láti ayérayé. Ó ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn ní àkókò tí ó wọ̀ fún un ninu iwaasu tí ó ti fi lé mi lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà Ọlọrun Olùgbàlà wa.
Mò ń kọ ìwé yìí sí Titu, ọmọ mi tòótọ́ ninu ẹ̀sìn igbagbọ kan náà.
Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba, ati Kristi Jesu Olùgbàlà wa, wà pẹlu rẹ̀.
Ìdí tí mo ṣe fi ọ́ sílẹ̀ ní Kirete ni pé kí o ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí ó kù tí kò dára tó, kí o sì yan àwọn àgbà lórí ìjọ ní gbogbo ìlú, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlànà fún ọ. Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìlẹ́gàn, tí ó ní ẹyọ iyawo kan, tí àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ onigbagbọ, tí ẹnìkan kò lè fi ẹ̀sùn kàn pé ó ń hùwà wọ̀bìà tabi pé ó jẹ́ alágídí. Nítorí alabojuto ìjọ níláti jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn gẹ́gẹ́ bí ìríjú Ọlọrun. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí yóo máa ṣe ti inú ara rẹ̀, tabi kí ó jẹ́ onínúfùfù. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà, tabi ẹni tí ó ní ìwọ̀ra nípa ọ̀rọ̀ owó. Ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn ati máa ṣe àlejò, tí ó sì fẹ́ ohun rere, ó yẹ kí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, olódodo, olùfọkànsìn, ẹni tí ó ń kó ara rẹ̀ níjàánu. Kí ó di ọ̀rọ̀ tòótọ́ tí a ti fi kọ́ ọ mú ṣinṣin, kí ó baà lè ní ọ̀rọ̀ ìwúrí nípa ẹ̀kọ́ tí ó yè, kí ó sì lè bá àwọn alátakò wí.
Nítorí àwọn alágídí pọ̀, tí wọn ń sọ̀rọ̀ asán, àwọn ẹlẹ́tàn, pàápàá jùlọ lára àwọn ọ̀kọlà. Dandan ni kí o pa wọ́n lẹ́nu mọ́, nítorí pé wọ́n ń da odidi agbo-ilé rú, wọ́n sì ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ tí kò tọ́ nítorí èrè tí kò yẹ.
Ẹnìkan ninu wọn tí ó jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn wolii wọn sọ pé, “Òpùrọ́ paraku ni àwọn ará Kirete, ẹhànnà, ẹranko, ọ̀lẹ, alájẹkì.” Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí náà má gbojú fún wọn, bá wọn wí kí wọ́n lè ní igbagbọ tí ó pé. Kí wọn má máa lo àkókò wọn lórí ìtàn àròsọ àwọn Juu ati ìlànà àwọn eniyan tí wọ́n ti yapa kúrò lọ́nà òtítọ́. Gbogbo nǹkan ni ó mọ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ṣugbọn kò sí nǹkankan tí ó mọ́ fún àwọn alaigbagbọ tí èrò wọn ti wọ́, nítorí èrò wọn ati ẹ̀rí ọkàn wọn ti wọ́. Wọ́n ń fi ẹnu jẹ́wọ́ pé àwọn mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọ́n ń sẹ́ ẹ ninu ìwà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹlẹ́gbin ati aláìgbọràn, wọn kò yẹ fún iṣẹ́ rere kan.