ROMU 8:9-14

ROMU 8:9-14 YCE

Ṣugbọn ní tiyín, ẹ kò hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí mọ́; Ẹ̀mí ló ń ṣamọ̀nà yín, bí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń gbé inú yín nítòótọ́. Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ní Ẹ̀mí Kristi ninu rẹ̀, kì í ṣe ti Kristi. Ṣugbọn bí Kristi bá ń gbé inú yín, bí ara yín yóo tilẹ̀ kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀, sibẹ ẹ̀mí yín yóo wà láàyè nítorí pé Ọlọrun ti da yín láre. Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Ọlọrun, ẹni tí ó jí Jesu dìde kúrò ninu òkú, bá ń gbé inú yín, òun náà tí ó jí Kristi dìde kúrò ninu òkú yóo sọ ara yín, tí yóo kú, di alààyè nípa Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó ń gbé inú yín. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kò sí ohunkohun mọ́ tí ó mú wa ní túlààsì pé kí á máa hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí. Nítorí bí ẹ bá hùwà bí àwọn tí ẹran-ara ń darí, kíkú ni ẹ óo kú dandan. Ṣugbọn tí ẹ bá ń rìn lọ́nà ti Ẹ̀mí, tí ẹ kò sì hu ìwà ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ẹ óo yè. Nítorí àwọn tí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń darí ni ọmọ Ọlọrun.