Nítorí pé gbogbo ẹ̀dá ayé ló ti pasán, kì í ṣe pé ẹ̀dá ayé fúnra wọn ni wọ́n fẹ́ pasán, ṣugbọn bẹ́ẹ̀ ni ó wu Ẹlẹ́dàá láti yàn án. Sibẹ ìrètí ń bẹ pé: ẹ̀dá ayé pàápàá yóo bọ́ lóko ẹrú, kúrò ninu ipò ìdíbàjẹ́, yóo sì pín ninu ọlá àwọn ọmọ Ọlọrun. Àwa náà rí i pé, títí di òní olónìí, gbogbo ẹ̀dá ayé ni wọ́n ń jẹ̀rora, tí wọ́n sì ń rọbí bí aboyún. Ṣugbọn kì í ṣe ẹ̀dá ayé nìkan ló ń jẹ̀rora. Àní sẹ́, àwa fúnra wa, tí a ti rí Ẹ̀mí Ọlọrun gbà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn rẹ̀ àkọ́kọ́, à ń jẹ̀rora lọ́kàn wa, bí a ti ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo pè wá lọ́mọ rẹ̀, tí yóo sì dá gbogbo ara wa nídè.
Kà ROMU 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ROMU 8:20-23
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò