ROMU 7:23-25

ROMU 7:23-25 YCE

Ṣugbọn bí mo ti wòye, àwọn ẹ̀yà ara mi ń tọ ọ̀nà mìíràn, tí ó lòdì sí ọ̀nà tí ọkàn mi fẹ́, ọ̀nà òdì yìí ni ó gbé mi sinu ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu àwọn ẹ̀yà ara mi. Irú ẹ̀dá wo tilẹ̀ ni tèmi yìí! Ta ni yóo gbà mí lọ́wọ́ ara tí ó fẹ́ ṣekú pa mí yìí? Háà! Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun! Òun nìkan ló lè gbà mí là nípa Jesu Kristi Oluwa wa. Bí ọ̀rọ̀ ara mi ti wá rí nìyí: ní ìdà kinni, mò ń tẹ̀lé ìlànà òfin Ọlọrun ninu àwọn èrò ọkàn mi: ní ìdà keji ẹ̀wẹ̀, èmi yìí kan náà, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran-ara, mo tún ń tọ ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀.