ROMU 5:15-21

ROMU 5:15-21 YCE

Kì í ṣe bí eniyan ṣe rú òfin tó ni Ọlọrun fi ń wọn ìfẹ́ ati àánú rẹ̀. Bí gbogbo eniyan bá jogún ikú nítorí aṣemáṣe ẹnìkan, oore-ọ̀fẹ́ ati àánú tí Ọlọrun fún gbogbo eniyan láti ọwọ́ ẹnìkan, àní Jesu Kristi, ó pọ̀ pupọ; ó pọ̀ ju ogún ikú lọ. Kì í ṣe ẹnìkan tí ó dẹ́ṣẹ̀ ni Ọlọrun ń wò kí ó tó ta àwọn eniyan lọ́rẹ. Ẹnìkan ló fa ìdájọ́ Ọlọrun. Ẹ̀bi ni a sì rí gbà ninu rẹ̀. Ṣugbọn àánú tí Ọlọrun fún wa dípò ọpọlọpọ aṣemáṣe wa, ìdáláre ni ó yọrí sí. Bí ikú bá torí òfin tí ẹnìkan rú jọba lé wa lórí, àwọn tí ó ti gba ibukun lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí wọ́n sì gba ìdáláre lọ́fẹ̀ẹ́, yóo ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ: wọn óo jọba, wọn óo sì yè pẹlu àṣẹ ẹnìkan, Jesu Kristi. Nítorí náà, bí òfin tí ẹnìkan rú ṣe ti gbogbo ọmọ aráyé sinu ìdájọ́ ikú, bẹ́ẹ̀ náà ni iṣẹ́ rere ẹnìkan yóo yọ gbogbo ọmọ aráyé ninu ìdájọ́ ikú sí ìyè. Bí a ti sọ gbogbo eniyan di ẹlẹ́ṣẹ̀ nítorí àìgbọràn ẹnìkan, bẹ́ẹ̀ náà ni a óo torí ìgbọràn ẹnìkan dá gbogbo eniyan láre. Ọ̀nà ẹ̀bùrú ni òfin gbà wọlé, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè pọ̀ jantirẹrẹ. Níbi tí ẹ̀ṣẹ̀ bá sì ti pọ̀, oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun a máa pọ̀ ju bí ẹ̀ṣẹ̀ ti pọ̀ tó lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, bí ikú ṣe sọ ẹ̀ṣẹ̀ di ọba, bẹ́ẹ̀ ni ìdáláre náà ń fi oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun jọba, ó sì mú wa wọnú ìyè ainipẹkun nípasẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú ROMU 5:15-21