Mo fẹ́ kí ẹ gba Febe bí arabinrin wa, ẹni tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọ tí ó wà ní Kẹnkiria. Ẹ gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀ ní orúkọ Kristi gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ onigbagbọ. Kí ẹ ràn án lọ́wọ́ ní ọ̀nàkọ́nà tí ó bá fẹ́; nítorí ó jẹ́ ẹni tí ó ran ọpọlọpọ eniyan ati èmi pàápàá lọ́wọ́. Ẹ kí Pirisila ati Akuila, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi ninu iṣẹ́ Kristi Jesu. Wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti gbà mí lọ́wọ́ ikú. Èmi nìkan kọ́ ni mo dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn, gbogbo ìjọ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu náà dúpẹ́ pẹlu. Ẹ kí ìjọ tí ó wà ní ilé wọn náà. Ẹ kí Epenetu àyànfẹ́ mi, ẹni tí ó jẹ́ onigbagbọ kinni ní ilẹ̀ Esia. Ẹ kí Maria, ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ pupọ láàrin yín. Ẹ kí Andironiku ati Junia, àwọn ìbátan mi tí a jọ wà lẹ́wọ̀n. Olókìkí ni wọ́n láàrin àwọn òjíṣẹ́ Kristi, wọ́n sì ti di onigbagbọ ṣiwaju mi. Ẹ kí Ampiliatu àyànfẹ́ mi ninu Oluwa. Ẹ kí Ubanu alábàáṣiṣẹ́ mi ninu iṣẹ́ Kristi ati Sitaku àyànfẹ́ mi. Ẹ kí Apele, akikanju onigbagbọ. Ẹ kí àwọn ará ilé Arisitobulu. Ẹ kí Hẹrodioni ìbátan mi. Ẹ kí àwọn ará ilé Nakisu tí wọ́n jẹ́ onigbagbọ. Ẹ kí Tirufina ati Tirufosa, àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ Oluwa. Ẹ kí Pasisi, arabinrin àyànfẹ́ tí ó ti ṣiṣẹ́ pupọ ninu Oluwa. Ẹ kí Rufọsi, àṣàyàn onigbagbọ ati ìyá rẹ̀ tí ó tún jẹ́ ìyá tèmi náà.
Kà ROMU 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ROMU 16:1-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò