Ǹjẹ́, mo bèèrè: ṣé Ọlọrun ti wá kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀ ni? Rárá o! Ọmọ Israẹli ni èmi fúnra mi. Ìran Abrahamu ni mí, láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Bẹnjamini. Ọlọrun kò kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀, àwọn tí ó ti yàn láti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Tabi ẹ kò mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ninu ìtàn Elija? Ó ní, “Oluwa, wọ́n ti pa àwọn wolii rẹ, wọ́n ti wó pẹpẹ ìrúbọ rẹ, èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń wá mi láti pa.” Ṣugbọn kí ni Ọlọrun wí fún un? Ó ní “Ẹẹdẹgbaarin (7,000) eniyan ṣì kù fún mi tí wọn kò tíì wólẹ̀ bọ Baali rí.” Bẹ́ẹ̀ náà ló rí ní àkókò yìí, àwọn kan kù tí Ọlọrun yàn nítorí oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. Tí ó bá wá jẹ́ pé nítorí oore-ọ̀fẹ́ ni Ọlọrun fi yàn wọ́n, kò tún lè jẹ́ nítorí iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, oore-ọ̀fẹ́ kò ní jẹ́ oore-ọ̀fẹ́ mọ́.
Kà ROMU 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ROMU 11:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò