ÌFIHÀN 5:6-14

ÌFIHÀN 5:6-14 YCE

Mo bá rí Ọ̀dọ́ Aguntan tí ó dúró láàrin ìtẹ́ náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà yí i ká. Ọ̀dọ́ Aguntan náà dàbí ẹni pé wọ́n ti pa á. Ìwo meje ni ó ní ati ojú meje. Àwọn ojú meje yìí ni Ẹ̀mí Ọlọrun meje tí Ọlọrun rán sí gbogbo orílẹ̀ ayé. Ọ̀dọ́ Aguntan náà bá wá, ó sì gba ìwé náà ní ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́. Nígbà tí ó gbà á, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn mẹrinlelogun náà dojúbolẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Aguntan yìí. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mú hapu kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́, ati àwo wúrà kéékèèké, tí ó kún fún turari. Turari yìí ni adura àwọn eniyan Ọlọrun, àwọn onigbagbọ. Wọ́n wá ń kọ orin titun kan, pé, “Ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ìwé náà, ati láti tú èdìdì ara rẹ̀. Nítorí wọ́n pa ọ́, o sì ti fi ẹ̀jẹ̀ rẹ bá Ọlọrun ṣe ìràpadà eniyan, láti inú gbogbo ẹ̀yà, ati gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè. O ti sọ wọ́n di ìjọba ti alufaa láti máa sin Ọlọrun wa. Wọn yóo máa jọba ní ayé.” Bí mo tí ń wò, mo gbọ́ ohùn ọpọlọpọ àwọn angẹli tí wọ́n yí ìtẹ́ náà ká ati àwọn ẹ̀dá alààyè ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun. Àwọn angẹli náà pọ̀ pupọ: ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹrun àìmọye. Wọ́n ń kígbe pé, “Ọ̀dọ́ Aguntan tí a ti pa ni ó tọ́ sí láti gba agbára, ọrọ̀, ọgbọ́n, ipá, ọlá, ògo ati ìyìn.” Mo bá tún gbọ́ tí gbogbo ẹ̀dá tí ó wà lọ́run ati ní orílẹ̀ ayé, ati nísàlẹ̀ ilẹ̀, ati lórí òkun, ati ohun gbogbo tí ń bẹ ninu òkun, ń wí pé, “Ìyìn, ọlá, ògo, ati agbára ni ti ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ati Ọ̀dọ́ Aguntan lae ati laelae.” Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá dáhùn pé, “Amin!” Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun sì dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun.