ORIN DAFIDI 36:8-10

ORIN DAFIDI 36:8-10 YCE

Wọ́n ń rí oúnjẹ jẹ ní àjẹyó ní ilé rẹ; nǹkan mímu tí ń ṣàn bí odò, ni o sì ń fún wọn mu. Nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà; ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a ti ń rí ìmọ́lẹ̀. Túbọ̀ máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ han àwọn tí ó mọ̀ ọ́, sì máa fi òdodo rẹ han àwọn ọlọ́kàn mímọ́.