OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga kan ọ̀run; òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run. Òtítọ́ rẹ dàbí òkè ńlá; ìdájọ́ rẹ sì jìn bí ibú omi. OLUWA, àtènìyàn, àtẹranko ni ò ń gbàlà. Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ níye lórí pupọ, Ọlọrun! Àwọn ọmọ eniyan a máa sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ. Wọ́n ń rí oúnjẹ jẹ ní àjẹyó ní ilé rẹ; nǹkan mímu tí ń ṣàn bí odò, ni o sì ń fún wọn mu. Nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà; ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a ti ń rí ìmọ́lẹ̀.
Kà ORIN DAFIDI 36
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 36:5-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò