Ẹ̀ṣẹ̀ ń gbin lọ́kàn eniyan burúkú, kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ninu èrò tirẹ̀. Nítorí pé lọ́kàn rẹ̀ a máa pọ́n ara rẹ̀, pé kò sí ẹni tí ó lè rí ẹ̀ṣẹ̀ òun, ká tó wá sọ pé yóo dá òun lẹ́bi. Ọ̀rọ̀ ìkà ati ẹ̀tàn ni ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀. Ó ti dáwọ́ ire ṣíṣe dúró; kò sì hu ìwà ọlọ́gbọ́n mọ́. A máa pète ìkà lórí ibùsùn rẹ̀; a máa rin ọ̀nà tí kò tọ́; kò sì kórìíra ibi. OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga kan ọ̀run; òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run. Òtítọ́ rẹ dàbí òkè ńlá; ìdájọ́ rẹ sì jìn bí ibú omi. OLUWA, àtènìyàn, àtẹranko ni ò ń gbàlà. Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ níye lórí pupọ, Ọlọrun! Àwọn ọmọ eniyan a máa sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ. Wọ́n ń rí oúnjẹ jẹ ní àjẹyó ní ilé rẹ; nǹkan mímu tí ń ṣàn bí odò, ni o sì ń fún wọn mu. Nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà; ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a ti ń rí ìmọ́lẹ̀. Túbọ̀ máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ han àwọn tí ó mọ̀ ọ́, sì máa fi òdodo rẹ han àwọn ọlọ́kàn mímọ́. Má jẹ́ kí àwọn agbéraga borí mi, má sì jẹ́ kí àwọn eniyan burúkú lé mi kúrò. Ẹ wo àwọn aṣebi níbi tí wọ́n ṣubú sí; wọ́n dà wólẹ̀, wọn kò sì le dìde.
Kà ORIN DAFIDI 36
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 36:1-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò