ORIN DAFIDI 35:1-16

ORIN DAFIDI 35:1-16 YCE

OLUWA, gbógun ti àwọn tí ń gbógun tì mí; gbé ìjà ko àwọn tí ń bá mi jà! Gbá asà ati apata mú, dìde, kí o sì ràn mí lọ́wọ́! Fa ọ̀kọ̀ yọ kí o sì dojú kọ àwọn tí ń lépa mi! Ṣe ìlérí fún mi pé, ìwọ ni olùgbàlà mi. Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi, kí wọn ó tẹ́! Jẹ́ kí àwọn tí ń gbìmọ̀ ibi sí mi dààmú, kí wọ́n sì sá pada sẹ́yìn! Kí wọ́n dàbí fùlùfúlù ninu afẹ́fẹ́, kí angẹli OLUWA máa lé wọn lọ! Jẹ́ kí ojú ọ̀nà wọn ṣóòkùn, kí ó sì máa yọ̀, kí angẹli OLUWA máa lépa wọn! Nítorí wọ́n dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi láìnídìí, wọ́n sì gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí láìnídìí. Jẹ́ kí ìparun dé bá wọn lójijì, jẹ́ kí àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ dè mí mú wọn; jẹ́ kí wọ́n kó sinu rẹ̀, kí wọ́n sì parun! Nígbà náà ni n óo máa yọ̀ ninu OLUWA, n óo sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìgbàlà rẹ̀. N óo fi gbogbo ara wí pé, “OLUWA, ta ni ó dàbí rẹ? Ìwọ ni ò ń gba aláìlágbára lọ́wọ́ ẹni tí ó lágbára tí o sì ń gba aláìlágbára ati aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ó fẹ́ fi wọ́n ṣe ìjẹ.” Àwọn tí ń fi ìlara jẹ́rìí èké dìde sí mi; wọ́n ń bi mí léèrè ohun tí n kò mọ̀dí. Wọ́n fi ibi san oore fún mi, ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì. Bẹ́ẹ̀ sì ni, ní tèmi, nígbà tí wọn ń ṣàìsàn, aṣọ ọ̀fọ̀ ni mo wọ̀; mo fi ààwẹ̀ jẹ ara mi níyà; mo gbadura pẹlu ìtẹríba patapata, bí ẹni pé mò ń ṣọ̀fọ̀ ọ̀rẹ́ mi, tabi arakunrin mi; mò ń lọ káàkiri, bí ẹni tí ń pohùnréré ẹkún ìyá rẹ̀, mo doríkodò, mo sì ń ṣọ̀fọ̀. Ṣugbọn nígbà tí èmi kọsẹ̀, wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n ń yọ̀, wọ́n kó tì mí; pàápàá jùlọ, àwọn àlejò tí n kò mọ̀ rí bẹ̀rẹ̀ sí purọ́ mọ́ mi léraléra. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pẹ̀gàn mi, wọ́n ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n sì ń wò mí bíi pé kí n kú.