Tọkàntọkàn ni mo fi ń ké pè ọ́, OLUWA, dá mi lóhùn; n óo sì máa tẹ̀lé ìlànà rẹ. Mo ké pè ọ́; gbà mí, n óo sì máa mú àṣẹ rẹ ṣẹ. Mo jí ní òwúrọ̀ kutukutu, mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́; mò ń retí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ rẹ. N kò fi ojú ba oorun ní gbogbo òru, kí n lè máa ṣe àṣàrò lórí ọ̀rọ̀ rẹ. Gbóhùn mi nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, OLÚWA, dá mi sí nítorí òtítọ́ rẹ. Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi súnmọ́ tòsí; wọ́n jìnnà sí òfin rẹ. Ṣugbọn ìwọ wà nítòsí, OLUWA, òtítọ́ sì ni gbogbo òfin rẹ. Ó pẹ́ tí mo ti kọ́ ninu ìlànà rẹ, pé o ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae. Wo ìpọ́njú mi, kí o gbà mí, nítorí n kò gbàgbé òfin rẹ. Gba ẹjọ́ mi rò, kí o sì gbà mí, sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Ìgbàlà jìnnà sí àwọn eniyan burúkú, nítorí wọn kò wá ìlànà rẹ. Àánú rẹ pọ̀, OLUWA, sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ rẹ. Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi ati àwọn ọ̀tá mi pọ̀, ṣugbọn n kò yapa kúrò ninu ìlànà rẹ. Mò ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀ pẹlu ìríra, nítorí wọn kì í pa òfin rẹ mọ́. Wo bí mo ti fẹ́ ẹ̀kọ́ rẹ tó! Dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ, gbogbo òfin òdodo rẹ ni yóo máa wà títí lae.
Kà ORIN DAFIDI 119
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 119:145-160
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò