ORIN DAFIDI 119:108-142

ORIN DAFIDI 119:108-142 YCE

Gba ẹbọ ìyìn àtọkànwá mi, OLUWA, kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Ayé mi wà ninu ewu nígbà gbogbo, ṣugbọn n kò gbàgbé òfin rẹ. Àwọn eniyan burúkú ti dẹ okùn sílẹ̀ dè mí, ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀. Ìlànà rẹ ni ogún mi títí lae, nítorí pé òun ni ayọ̀ mi. Mo ti pinnu láti máa tẹ̀lé ìlànà rẹ nígbà gbogbo, àní, títí dé òpin. Mo kórìíra àwọn oníyèméjì, ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ. Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi ati asà mi, mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin aṣebi, kí n lè pa òfin Ọlọrun mi mọ́. Gbé mi ró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, kí n lè wà láàyè, má sì dójú ìrètí mi tì mí. Gbé mi ró, kí n lè wà láìléwu, kí n lè máa ka ìlànà rẹ sí nígbà gbogbo. O ti kọ gbogbo àwọn tí ó yapa kúrò ninu ìlànà rẹ sílẹ̀, nítorí pé asán ni gbogbo ẹ̀tàn wọn. O ti pa àwọn eniyan burúkú tì, bí ìdàrọ́ irin, nítorí náà ni mo ṣe fẹ́ràn ìlànà rẹ. Mo wárìrì nítorí pé mo bẹ̀rù rẹ, mo sì bẹ̀rù ìdájọ́ rẹ. Mo ti ṣe ohun tí ó tọ́ tí ó sì yẹ, má fi mí sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń ni mí lára. Ṣe ìlérí ìrànlọ́wọ́ fún ire èmi iranṣẹ rẹ, má sì jẹ́ kí àwọn onigbeeraga ni mí lára. Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi, níbi tí mo tí ń retí ìgbàlà rẹ, ati ìmúṣẹ ìlérí òdodo rẹ. Ṣe sí èmi iranṣẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Iranṣẹ rẹ ni mí, fún mi lóye, kí n lè mọ ìlànà rẹ. OLUWA, ó tó àkókò fún ọ láti ṣe nǹkankan, nítorí àwọn eniyan ń rú òfin rẹ. Nítorí náà ni èmi ṣe fẹ́ràn òfin rẹ ju wúrà lọ; àní, ju ojúlówó wúrà. Nítorí náà, èmi ń tẹ̀lé gbogbo ẹ̀kọ́ rẹ, mo sì kórìíra gbogbo ọ̀nà èké. Òfin rẹ dára, nítorí náà ni mo ṣe ń pa wọ́n mọ́. Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ a máa fúnni ní ìmọ́lẹ̀, a sì máa fi òye fún àwọn onírẹ̀lẹ̀. Mo la ẹnu, mò ń mí hẹlẹ, nítorí pé mò ń lépa òfin rẹ. Kọjú sí mi kí o ṣe mí lóore bí o ti máa ń ṣe sí àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ. Mú ẹsẹ̀ mi dúró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, má sì jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ kankan jọba lórí mi. Gbà mí lọ́wọ́ ìnilára àwọn eniyan, kí n lè máa tẹ̀lé ìlànà rẹ. Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí ara èmi iranṣẹ rẹ; kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Omijé ń dà lójú mi pòròpòrò, nítorí pé àwọn eniyan kò pa òfin rẹ mọ́. Olódodo ni ọ́, OLUWA, ìdájọ́ rẹ sì tọ́. Òdodo ni o fi pa àṣẹ rẹ, òtítọ́ patapata ni. Mò ń tara gidigidi, nítorí pé àwọn ọ̀tá mi gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ. A ti yẹ ọ̀rọ̀ rẹ wò fínnífínní, ó dúró ṣinṣin, mo sì fẹ́ràn rẹ̀. Bí mo tilẹ̀ kéré, tí ayé sì kẹ́gàn mi, sibẹ n kò gbàgbé ìlànà rẹ. Òdodo rẹ wà títí lae, òtítọ́ sì ni òfin rẹ.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú ORIN DAFIDI 119:108-142