Yóo gbọ́ adura àwọn aláìní, kò sì ní kẹ́gàn ẹ̀bẹ̀ wọn. Kí ẹ kọ èyí sílẹ̀ fún ìran tí ń bọ̀, kí àwọn ọmọ tí a kò tíì bí lè máa yin OLUWA, pé OLUWA bojú wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀, láti ọ̀run ni ó ti bojú wo ayé; láti gbọ́ ìkérora àwọn ìgbèkùn, ati láti dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sílẹ̀. Kí á lè pòkìkí orúkọ OLUWA ní Sioni, kí á sì máa yìn ín lógo ní Jerusalẹmu, nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè bá péjọ tàwọn tọba wọn, láti sin OLUWA. Ó ti gba agbára mi ní àìpé ọjọ́, ó ti gé ọjọ́ ayé mi kúrú. Mo ní, “Áà! Ọlọrun mi, má mú mi kúrò láyé láìpé ọjọ́, ìwọ tí ọjọ́ ayé rẹ kò lópin.” Láti ìgbà laelae ni o ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sì ni ọ̀run. Wọn óo parẹ́ ṣugbọn ìwọ yóo wà títí lae; gbogbo wọn yóo gbó bí aṣọ, o óo pààrọ̀ wọn bí aṣọ; wọn yóo sì di ohun ìpatì. Ṣugbọn ìwọ wà bákan náà, ọjọ́ ayé rẹ kò sì lópin. Ọmọ àwọn iranṣẹ rẹ yóo ní ibùgbé; bẹ́ẹ̀ ni arọmọdọmọ wọn yóo fẹsẹ̀ múlẹ̀ níwájú rẹ.
Kà ORIN DAFIDI 102
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 102:17-28
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò