ÌWÉ ÒWE 5:1-20

ÌWÉ ÒWE 5:1-20 YCE

Ọmọ mi fetí sí ọgbọ́n tí mò ń kọ́ ọ, tẹ́tí rẹ sí òye mi, kí o baà lè ní làákàyè, kí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ lè kún fún ìmọ̀. Nítorí ẹnu alágbèrè obinrin a máa dùn bí oyin, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì tuni lára ju òróró lọ, ṣugbọn níkẹyìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ á korò bí iwọ, ẹnu rẹ̀ á sì mú bí idà olójú meji. Ẹsẹ̀ rẹ̀ ń dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ lọ sinu ikú, ìgbésẹ̀ rẹ̀ sì lọ tààrà sinu ibojì. Ó kọ̀ láti rin ọ̀nà ìyè, ọ̀nà rẹ̀ wọ́, kò sì mọ̀. Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ẹ má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu. Ẹ jìnnà sí alágbèrè obinrin, kí ẹ má tilẹ̀ súnmọ́ ẹnu ọ̀nà rẹ̀, kí ẹ má baà gbé ògo yín fún ẹlòmíràn, kí ẹ sì fi ìgbé ayé yín lé aláìláàánú lọ́wọ́. Kí àjèjì má baà jèrè iṣẹ́ yín, kí làálàá rẹ má sì bọ́ sápò àlejò. Kí o má baà kérora nígbẹ̀yìn ayé rẹ, nígbà tí o bá di ìjẹ fún ẹni ẹlẹ́ni nígbà náà ni o óo wí pé, “Kí ló dé tí mo kórìíra ìtọ́ni, tí ọkàn mi sì kẹ́gàn ìbáwí! N kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn olùkọ́ mi n kò sì gba ti àwọn tí wọn ń tọ́ mi sọ́nà. Èyí ni ó sún mi dé etí bèbè ìparun, láàrin àwùjọ eniyan.” Ìwọ ọkọ, láti inú àmù rẹ ni kí o ti máa mu omi; omi tí ń sun láti inú kànga rẹ ni kí o máa mu. Kò dára kí orísun rẹ máa ṣàn káàkiri, bí omi àgbàrá ní gbogbo òpópónà. Tìrẹ nìkan ṣoṣo ni kí ó jẹ́, má jẹ́ kí àjèjì bá ọ pín ninu rẹ̀. Jẹ́ kí orísun rẹ ní ibukun, kí inú rẹ sì máa dùn sí iyawo tí o fi àárọ̀ gbé. Olólùfẹ́ rẹ tí ó dára bí abo egbin. Jẹ́ kí ẹwù rẹ̀ máa mú inú rẹ dùn nígbà gbogbo, kí ìfẹ́ rẹ̀ máa mú orí rẹ yá nígbàkúùgbà. Kí ló dé, ọmọ mi, tí ìfẹ́ alágbèrè obinrin yóo fi wọ̀ ọ́ lọ́kàn, tí o óo fi máa dìrọ̀ mọ́ obinrin olobinrin?