Ta ló lè rí iyawo tí ó ní ìwà rere fẹ́?
Ó ṣọ̀wọ́n ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ.
Ọkọ rẹ̀ yóo fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé e,
kò sì ní ṣaláì ní ohunkohun.
Rere ni obinrin náà máa ń ṣe fún un
kò ní ṣe é níbi, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
A máa lọ wá irun aguntan ati òwú ìhunṣọ,
a sì máa fi tayọ̀tayọ̀ hun aṣọ.
Obinrin náà dàbí ọkọ̀ ojú omi oníṣòwò,
tí ó ń mú oúnjẹ wálé láti ọ̀nà jíjìn réré.
Ìdájí níí tií jí láti wá oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀,
ati láti yan iṣẹ́ fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀.
Bí ó bá rí ilẹ̀ oko, a yẹ̀ ẹ́ wò, a sì rà á,
a sì fi èrè iṣẹ́ rẹ̀ gbin ọgbà àjàrà.
A fi agbára fún ọ̀já mọ́nú,
a sì tẹpá mọ́ṣẹ́.
A máa mójútó ọjà tí ó ń tà,
fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú lóru.
Ó fi ọwọ́ lé kẹ̀kẹ́ òwú,
ó sì ń ran òwú.
Ó lawọ́ sí àwọn talaka,
a sì máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́.
Kì í bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ nígbà òtútù,
nítorí gbogbo wọn ni ó ti bá hun aṣọ tí ó móoru.
A máa hun aṣọ ọlọ́nà a sì fi bo ibùsùn rẹ̀,
òun náà á wọ aṣọ funfun dáradára ati ti elése àlùkò.
Wọ́n dá ọkọ rẹ̀ mọ̀ lẹ́nu ibodè,
nígbà tí ó bá jókòó pẹlu àwọn àgbààgbà ìlú.
A máa hun aṣọ funfun, a sì tà wọ́n,
a máa ta ọ̀já ìgbànú fún àwọn oníṣòwò.
Agbára ati ọlá ni ó fi ń bora bí aṣọ,
ó sì ní ìrètí ayọ̀ nípa ọjọ́ iwájú.
Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ní ń jáde láti ẹnu rẹ̀,
a sì máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ àánú.
A máa ṣe ìtọ́jú ìdílé rẹ̀ dáradára,
kì í sì í hùwà ọ̀lẹ.
Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa pè é ní ẹni ibukun,
ọkọ rẹ̀ pẹlu a sì máa yìn ín pé,
“Ọpọlọpọ obinrin ni wọ́n ti ṣe ribiribi,
ṣugbọn ìwọ ta gbogbo wọn yọ.”
Ẹ̀tàn ni ojú dáradára, asán sì ni ẹwà,
obinrin tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni ó yẹ kí á yìn.
Fún un ninu èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,
jẹ́ kí wọn máa yìn ín lẹ́nu ibodè nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.