ÌWÉ ÒWE 30:24-28

ÌWÉ ÒWE 30:24-28 YCE

Àwọn nǹkan mẹrin kan wà tí wọ́n kéré ninu ayé, sibẹsibẹ wọ́n gbọ́n lọpọlọpọ: àwọn èèrà kò lágbára, ṣugbọn wọn a máa kó oúnjẹ wọn jọ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Àwọn ehoro ìgbẹ́ kò lágbára, sibẹsibẹ wọ́n ń kọ́ ilé sí pàlàpálá òkúta. Àwọn eṣú kò ní ọba, sibẹsibẹ wọ́n ń rìn ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Eniyan lè fi ọwọ́ mú aláǹgbá, sibẹsibẹ wọ́n pọ̀ ní ààfin ọba.