ÌWÉ ÒWE 2:16-22

ÌWÉ ÒWE 2:16-22 YCE

A óo gbà ọ́ lọ́wọ́ obinrin oníṣekúṣe, àní lọ́wọ́ obinrin onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn rẹ̀. Ẹni tí ó kọ ọkọ àárọ̀ rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbàgbé majẹmu Ọlọrun rẹ̀. Ẹni tí ilé rẹ̀ rì sinu ìparun, tí ọ̀nà rẹ̀ sì wà ninu ọ̀fìn isà òkú. Kò sí ẹni tí ó tọ̀ ọ́ lọ, tí ó pada rí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í tún pada sí ọ̀nà ìyè. Nítorí náà, máa rìn ní ọ̀nà àwọn eniyan rere, sì máa bá àwọn olódodo rìn. Nítorí àwọn tí wọ́n dúró ṣinṣin ni wọn yóo máa gbé ilẹ̀ náà, àwọn olóòótọ́ inú ni yóo máa wà níbẹ̀, ṣugbọn a óo pa ẹni ibi run lórí ilẹ̀ náà, a óo sì fa alárèékérekè tu kúrò níbẹ̀.