Àwọn òwe tí Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli pa,
kí àwọn eniyan lè ní ọgbọ́n ati ẹ̀kọ́,
kí òye ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ lè yé wọn,
láti gba ẹ̀kọ́, tí yóo kọ́ni lọ́gbọ́n,
òdodo, ẹ̀tọ́ ati àìṣojúṣàájú,
láti kọ́ onírẹ̀lẹ̀ lọ́gbọ́n,
kí á sì fi ìmọ̀ ati làákàyè fún ọ̀dọ́,
kí ọlọ́gbọ́n lè gbọ́, kí ó sì fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀,
kí ẹni tí ó ní òye lè ní ìmọ̀ pẹlu.
Láti lè mọ òwe ati àkàwé ọ̀rọ̀,
ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ati àdììtú ọ̀rọ̀.
Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀,
ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa pẹ̀gàn ọgbọ́n ati ẹ̀kọ́.
Ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ẹ̀kọ́ baba rẹ,
má sì kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ,
nítorí pé ẹ̀kọ́ tí wọn bá kọ́ ọ yóo dàbí adé tí ó lẹ́wà lórí rẹ,
ati bí ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ.
Ìwọ ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́,
o ò gbọdọ̀ gbà.
Bí wọn bá wí pé,
“Tẹ̀lé wa ká lọ,
kí á lọ sápamọ́ láti paniyan,
kí á lúgọ de aláìṣẹ̀,
jẹ́ kí á gbé wọn mì láàyè
kí á gbé wọn mì lódidi bí isà òkú,
a óo rí àwọn nǹkan olówó iyebíye kó,
ilé wa yóo sì kún fún ìkógun.
Ìwọ ṣá darapọ̀ mọ́ wa,
kí á sì jọ lẹ̀dí àpò pọ̀.”
Ọmọ mi, má bá wọn kẹ́gbẹ́,
má sì bá wọn rìn,
nítorí ọ̀nà ibi ni ẹsẹ̀ wọn máa ń yá sí,
wọ́n a sì máa yára láti paniyan.
Asán ni àwọ̀n tí eniyan dẹ sílẹ̀,
nígbà tí ẹyẹ tí a dẹ ẹ́ fún ń woni,
ṣugbọn ẹ̀jẹ̀ ara wọn ni irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ lúgọ dè,
ìparun ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n lúgọ tí wọn ń retí.
Bẹ́ẹ̀ ni ti àwọn tí wọ́n ń fi ipá kó ọrọ̀ jọ rí,
ọrọ̀ tí wọn fi ipá kójọ níí gba ẹ̀mí wọn.