FILIPI 4:4-6
FILIPI 4:4-6 YCE
Ẹ máa yọ̀ ninu Oluwa nígbà gbogbo. Mo tún wí: ẹ máa yọ̀. Ẹ jẹ́ kí ó hàn sí gbogbo eniyan pé ẹ ní ẹ̀mí ìfaradà. Oluwa fẹ́rẹ̀ dé! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ohunkohun dààmú yín, ṣugbọn ninu gbogbo adura ati ẹ̀bẹ̀ yín, ẹ máa fi àwọn ìbéèrè yín siwaju Ọlọrun pẹlu ọpẹ́.






