NEHEMAYA 2:11-18

NEHEMAYA 2:11-18 YCE

Mo bá wá sí Jerusalẹmu mo sì wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹta. Mo gbéra ní alẹ́ èmi ati àwọn eniyan díẹ̀, ṣugbọn n kò sọ ohun tí Ọlọrun mi fi sí mi lọ́kàn láti ṣe ní Jerusalẹmu fún ẹnikẹ́ni. Kò sí ẹranko kankan pẹlu mi àfi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí mo gùn. Mo gbéra lóru, mo gba Ẹnubodè Àfonífojì. Mo jáde sí kànga Diragoni, mo gba ibẹ̀ lọ sí Ẹnubodè Ààtàn. Bí mo ti ń lọ, mò ń wo àwọn ògiri Jerusalẹmu tí wọ́n ti wó lulẹ̀ ati àwọn ẹnu ọ̀nà tí wọ́n ti jó níná. Lẹ́yìn náà, mo lọ sí Ẹnubodè Orísun ati ibi Adágún ọba, ṣugbọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí mo gùn kò rí ọ̀nà kọjá. Lóru náà ni mo gba àfonífojì Kidironi gòkè lọ, mo sì ṣe àyẹ̀wò odi náà yíká, lẹ́yìn náà, mo pẹ̀yìndà mo sì gba Ẹnubodè Àfonífojì wọlé pada. Àwọn ìjòyè náà kò sì mọ ibi tí mo lọ tabi ohun tí mo lọ ṣe, n kò sì tíì sọ nǹkankan fún àwọn Juu, ẹlẹgbẹ́ mi: àwọn alufaa, ati àwọn ọlọ́lá, tabi àwọn ìjòyè ati àwọn yòókù tí wọn yóo jọ ṣe iṣẹ́ náà. Lẹ́yìn náà, mo sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí irú ìyọnu tí ó dé bá wa! Ẹ wò ó bí Jerusalẹmu ṣe parun tí àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì jóná. Ẹ múra, ẹ jẹ́ kí á kọ́ odi Jerusalẹmu, kí á lè fi òpin sí ìtìjú tí ó dé bá wa.” Mo sọ fún wọn nípa bí Ọlọrun ṣe lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ mi ati nípa ọ̀rọ̀ tí ọba bá mi sọ. Wọ́n sì dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á múra kí á sì kọ́ ọ.” Wọ́n sì gbáradì láti ṣe iṣẹ́ rere náà.