NEHEMAYA 1:4-11

NEHEMAYA 1:4-11 YCE

Nígbà tí mo gbọ́ bẹ́ẹ̀, mo jókòó, mo sọkún, mo sì kẹ́dùn fún ọpọlọpọ ọjọ́. Mo bá bẹ̀rẹ̀ sí gbààwẹ̀, mo sì ń gbadura sí Ọlọrun ọ̀run pé, “OLUWA Ọlọrun ọ̀run, Ọlọrun tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, Ọlọrun tíí máa pa majẹmu ati ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ mọ́ pẹlu àwọn tí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, tẹ́tí sílẹ̀, bojú wò mí, kí o sì fetí sí adura èmi iranṣẹ rẹ, tí mò ń gbà tọ̀sán-tòru nítorí àwọn ọmọ Israẹli, iranṣẹ rẹ, tí mo sì ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ṣẹ̀ ọ́. Wò ó, èmi ati ìdílé baba mi ti dẹ́ṣẹ̀. A ti hùwà burúkú sí ọ, a kò sì pa àwọn òfin, ati ìlànà ati àṣẹ rẹ tí o pa fún Mose iranṣẹ rẹ mọ́. Ranti ìlérí tí o ṣe fún Mose, iranṣẹ rẹ, pé, ‘Bí ẹ kò bá jẹ́ olóòótọ́, n óo fọn yín káàkiri sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, ṣugbọn tí ẹ bá pada sọ́dọ̀ mi, tí ẹ pa òfin mi mọ́, tí ẹ sì ń tẹ̀lé e, bí ẹ tilẹ̀ fọ́nká lọ sí ọ̀nà jíjìn réré, n óo ṣà yín jọ, n óo sì ko yín pada sí ibi tí mo ti yàn pé ẹ óo ti máa sìn mí kí orúkọ mi lè máa wà níbẹ̀.’ “Iranṣẹ rẹ ni wọ́n, eniyan rẹ sì ni wọ́n, àwọn tí o ti fi ipá ati agbára ọwọ́ rẹ rà pada. OLUWA, tẹ́tí sí adura èmi iranṣẹ rẹ, tí mo bẹ̀rù orúkọ rẹ, kí o sì jẹ́ kí n ṣe àṣeyọrí lónìí, kí n sì rí ojurere ọba.” Èmi ni agbọ́tí ọba ní àkókò náà.