MAKU 6:34-44

MAKU 6:34-44 YCE

Nígbà tí Jesu jáde ninu ọkọ̀ ó rí ọpọlọpọ eniyan, àánú ṣe é nítorí wọ́n dàbí aguntan tí kò ní olùṣọ́. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ọpọlọpọ nǹkan. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, wọ́n wí fún un pé, “Aṣálẹ̀ nìhín yìí, ilẹ̀ sì ń ṣú lọ. Jẹ́ kí àwọn eniyan túká, kí wọn lè lọ sí àwọn abà ati abúlé tí ó wà yíká láti ra oúnjẹ fún ara wọn.” Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni kí ẹ fún wọn ní ohun tí wọn óo jẹ.” Wọ́n ní, “Ṣé kí á wá lọ ra oúnjẹ igba owó fadaka ni, kí a lè fún wọn jẹ!” Ó bi wọ́n pé, “Ìba oúnjẹ wo ni ẹ ní? Ẹ lọ wò ó.” Lẹ́yìn tí wọ́n wádìí, wọ́n ní “Burẹdi marun-un ni ati ẹja meji.” Ó bá pàṣẹ fún wọn kí gbogbo àwọn eniyan jókòó ní ìṣọ̀wọ́, ìṣọ̀wọ́ lórí koríko. Wọ́n bá jókòó lọ́wọ̀ọ̀wọ́, ní ọgọọgọrun-un ati ní aadọtọọta. Jesu bá mú burẹdi marun-un ati ẹja meji náà, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó dúpẹ́. Ó bá bu burẹdi náà, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọn pín in fún àwọn eniyan. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó pín ẹja meji náà fún gbogbo wọn. Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó. Wọ́n bá kó àjẹkù burẹdi ati ẹja jọ, ó kún agbọ̀n mejila. Iye àwọn ọkunrin tí ó jẹ oúnjẹ náà jẹ́ ẹgbẹẹdọgbọn (5000).