Bí ọkunrin kan tí ń jẹ́ Simoni, ará Kirene, baba Alẹkisanderu ati Rufọsi, ti ń ti ọ̀nà ìgbèríko bọ̀, bí ó ti ń kọjá lọ, wọ́n fi tipátipá mú un láti gbé agbelebu Jesu. Wọ́n wá mú Jesu lọ sí ibìkan tí à ń pè ní Gọlgọta (ìtumọ̀ èyí tíí ṣe “Ibi Agbárí”). Wọ́n fún un ní ọtí tí wọ́n ti po òjíá mọ́, ṣugbọn kò gbà á. Wọ́n bá kàn án mọ́ agbelebu. Wọ́n ṣẹ́ gègé lórí aṣọ rẹ̀ láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe pín àwọn aṣọ náà mọ́ ara wọn lọ́wọ́. Ní agogo mẹsan-an òwúrọ̀ ni wọ́n kàn án mọ́ agbelebu. Àkọlé orí agbelebu tí wọ́n kọ, tí ó jẹ́ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án ni: “Ọba àwọn Juu.”
Kà MAKU 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MAKU 15:21-26
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò