Bí wọ́n ti ń jẹun, Jesu mú burẹdi, ó gbadura sí i, ó bù ú, ó fún wọn. Ó ní, “Ẹ gbà, èyí ni ara mi.”
Ó tún mú ife, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bá gbé e fún wọn. Gbogbo wọn mu ninu rẹ̀. Ó wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí a fi dá majẹmu, ẹ̀jẹ̀ tí a ta sílẹ̀ fún ọpọlọpọ eniyan. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé n kò ní mu ninu èso àjàrà mọ́ títí di ọjọ́ tí n óo mu ún ní ọ̀tun ninu ìjọba Ọlọrun.”
Lẹ́yìn tí wọ́n kọ orin tán, wọ́n jáde lọ sí Òkè Olifi.
Jesu bá sọ fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ óo pada lẹ́yìn mi, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ọwọ́ yóo tẹ olùṣọ́-aguntan, àwọn aguntan yóo bá fọ́nká,’ Ṣugbọn lẹ́yìn tí a bá ti jí mi dìde, n óo ṣiwaju yín lọ sí Galili.”
Ṣugbọn Peteru wí fún un pé, “Bí gbogbo eniyan bá pada lẹ́yìn rẹ, èmi kò ní pada.”
Jesu wí fún un pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ní alẹ́ yìí kí àkùkọ tó kọ ní ẹẹmeji, ìwọ náà yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.”
Ṣugbọn Peteru tún tẹnu mọ́ ọn pé, “Bí ó bá kan ọ̀ràn pé kí n bá ọ kú, sibẹ n kò ní sẹ́ ọ!”
Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù ń wí.
Wọ́n dé ibìkan tí wọn ń pè ní Gẹtisemani. Ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí mo bá lọ gbadura.” Ó wá mú Peteru, Jakọbu ati Johanu pẹlu rẹ̀. Àyà bẹ̀rẹ̀ sí pá a, ó bẹ̀rẹ̀ sí dààmú. Ó wí fún wọn pé, “Ọkàn mi bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ lè kú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ máa ṣọ́nà.”
Ó bá lọ sí iwájú díẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó ń gbadura pé bí ó bá ṣeéṣe kí àkókò yìí kọjá lórí òun. Ó ní, “Baba, Baba, ohun gbogbo ṣeéṣe fún ọ. Mú kí ife kíkorò yìí kọjá kúrò lórí mi. Ṣugbọn ìfẹ́ tìrẹ ni kí o ṣe, kì í ṣe ìfẹ́ tèmi.”
Ó pada lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹta, ó rí i pé wọ́n ti sùn lọ! Ó wí fún Peteru pé, “Simoni, ò ń sùn ni? O kò lè ṣọ́nà fún wakati kan péré? Gbogbo yín, ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ tún máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò. Ẹ̀mí fẹ́ ṣe é, ṣugbọn ara kò lágbára.”
Ó tún lọ gbadura, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan náà bíi ti àkọ́kọ́. Ó tún wá, ó rí i pé wọ́n tún ń sùn, nítorí pé oorun ń kùn wọ́n pupọ. Wọn kò wá mọ ìdáhùn tí wọn ì bá fi fún un mọ́.
Ó pada wá ní ẹẹkẹta, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣì wà níbi tí ẹ̀ ń sùn, tí ẹ̀ ń gbádùn ìsinmi yín? Àbùṣe bùṣe! Àkókò náà tó. Wọn yóo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ. Ẹni tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá ti súnmọ́ tòsí.”
Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Judasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila dé, pẹlu àwọn eniyan tí ó mú idà ati kùmọ̀ lọ́wọ́. Wọ́n wá láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ati àwọn àgbà. Ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá ti fi àmì fún wọn. Ó ní, “Ẹni tí mo bá kí, tí mo fi ẹnu kàn ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ọkunrin náà. Ẹ mú un, kí ẹ fà á lọ, ẹ má jẹ́ kí ó bọ́.”
Lẹsẹkẹsẹ bí ó ti dé, Judasi lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, ó kí i, ó ní, “Olùkọ́ni!” Ó sì da ẹnu dé e ní ẹ̀rẹ̀kẹ́. Àwọn tí ó bá a wá bá ṣùrù mọ́ Jesu, wọ́n mú un. Ṣugbọn ọ̀kan ninu àwọn tí ó dúró fa idà yọ, ó fi ṣá ẹrú Olórí Alufaa, ó bá gé e létí. Jesu bá sọ fún wọn pé, “Ẹ mú idà ati kùmọ̀ lọ́wọ́ láti wá mú mi bí ẹni pé ẹ̀ ń bọ̀ wá mú ọlọ́ṣà? Lojoojumọ ni mo wà pẹlu yín ninu Tẹmpili tí mò ń kọ́ àwọn eniyan, ẹ kò ṣe mú mi nígbà náà. Ṣugbọn kí àkọsílẹ̀ lè ṣẹ ni èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀.”
Nígbà náà ni Gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá fi í sílẹ̀, wọ́n bá sálọ.
Ọdọmọkunrin kan tí ó jẹ́ pé aṣọ funfun nìkan ni ó dà bo ara ń tẹ̀lé e. Nígbà tí wọ́n gbá a mú, ó fi aṣọ ìbora rẹ̀ sílẹ̀, ó bá sálọ níhòòhò.