Wọ́n tún wá sí Jerusalẹmu. Bí Jesu ti ń rìn kiri ninu Tẹmpili, àwọn olórí alufaa, ati àwọn amòfin, ati àwọn àgbà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Wọ́n ń bi í pé, “Irú àṣẹ wo ni o fi ń ṣe nǹkan wọnyi? Ta ni ó fún ọ ní àṣẹ tí o fi ń ṣe wọ́n?” Jesu dá wọn lóhùn, ó ní, “N óo bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan, ẹ dá mi lóhùn, èmi náà óo wá sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi. Ìrìbọmi tí Johanu ń ṣe, láti ọ̀run ni ó ti gba àṣẹ ni, tabi láti ọwọ́ eniyan? Ẹ dá mi lóhùn.” Nígbà náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn jiyàn pé, “Bí a bá wí pé, ‘Láti ọ̀run ni,’ yóo sọ pé, ‘Kí ló dé tí ẹ kò fi gbà á gbọ́?’ Àbí kí a wí pé, ‘Láti ọwọ́ eniyan ni?’ ” Wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan nítorí gbogbo eniyan ni ó gbà pé wolii tòótọ́ ni Johanu. Wọ́n bá dá Jesu lóhùn pé, “Àwa kò mọ̀.” Nígbà náà ni Jesu sọ fún wọn pé, “Èmi náà kò ní sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi fun yín.”
Kà MAKU 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MAKU 11:27-33
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò