Wọ́n lọ sí Kapanaumu. Ní Ọjọ́ Ìsinmi àwọn Juu, Jesu lọ sí ilé ìpàdé, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan. Ẹnu ya àwọn tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀, nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, yàtọ̀ sí bí àwọn amòfin ṣe ń kọ́ wọn. Ọkunrin kan wà ninu ilé ìpàdé náà tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ó bá kígbe tòò, ó ní, “Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ará Nasarẹti? Ṣé o dé láti pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́. Ẹni Mímọ́ Ọlọrun ni ọ́.” Jesu bá bá a wí, ó ní, “Pa ẹnu mọ́, kí o jáde kúrò ninu ọkunrin yìí.” Ẹ̀mí èṣù náà bá gbo ọkunrin náà jìgìjìgì, ó kígbe tòò, ó sì jáde kúrò ninu ọkunrin náà.
Kà MAKU 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MAKU 1:21-26
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò