Ta ni ninu yín tí ó lè ṣe àníyàn títí tí ó lè fi kún ọjọ́ ayé rẹ̀? “Kí ní ṣe tí ẹ̀ ń ṣe àníyàn nípa ohun tí ẹ óo wọ̀? Ẹ ṣe akiyesi àwọn òdòdó inú igbó bí wọ́n ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú. Sibẹ mo sọ fun yín pé Solomoni pàápàá ninu gbogbo ìgúnwà rẹ̀ kò lè wọ aṣọ tí ó lẹ́wà bíi ti ọ̀kan ninu àwọn òdòdó yìí. Ǹjẹ́ bí Ọlọrun bá wọ koríko ìgbẹ́ láṣọ báyìí, koríko tí yóo wà lónìí, tí a óo fi dáná lọ́la, mélòó-mélòó ni yóo wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré? “Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn pé kí ni ẹ óo jẹ? Tabi, kí ni ẹ óo mu? Tabi kí ni ẹ óo fi bora? Nítorí gbogbo nǹkan wọnyi ni àwọn abọ̀rìṣà ń lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo wọn.
Kà MATIU 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MATIU 6:27-32
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò