MATIU 5:1-16

MATIU 5:1-16 YCE

Nígbà tí Jesu rí ọ̀pọ̀ eniyan, ó gun orí òkè lọ. Ó jókòó; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ń kọ́ wọn pé: “Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó jẹ́ òtòṣì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí Ọlọrun yóo tù wọ́n ninu. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀, nítorí wọn yóo jogún ayé. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ebi òdodo ń pa, tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ, nítorí Ọlọrun yóo bọ́ wọn ní àbọ́yó. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn aláàánú, nítorí Ọlọrun yóo ṣàánú wọn. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́, nítorí wọn yóo rí Ọlọrun. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó ń mú kí alaafia wà láàrin àwọn eniyan, nítorí Ọlọrun yóo pè wọ́n ní ọmọ rẹ̀. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí eniyan ń ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. “Ayọ̀ ń bẹ fun yín, tí wọ́n bá kẹ́gàn yín, tí wọ́n ṣe inúnibíni si yín, tí wọ́n bá ń fi èké sọ ọ̀rọ̀ burúkú lóríṣìíríṣìí si yín nítorí mi. Ẹ máa yọ̀, kí inú yín máa dùn, nítorí èrè yín pọ̀ ní ọ̀run. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wolii tí ó ti wà ṣiwaju yín. “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé; ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, kí ni yóo tún sọ ọ́ di iyọ̀ gidi mọ́? Kò wúlò fún ohunkohun mọ́ àfi kí á dà á nù, kí eniyan máa tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè, kò ṣe é gbé pamọ́. Wọn kì í tan fìtílà tán kí wọ́n fi igbá bò ó; lórí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n ń gbé e kà. Yóo wá fi ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ó wà ninu ilé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìmọ́lẹ̀ yín níláti máa tàn níwájú àwọn eniyan, kí wọn lè rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin Baba yín tí ó ń bẹ lọ́run lógo.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú MATIU 5:1-16