MATIU 27:45-56

MATIU 27:45-56 YCE

Láti agogo mejila ọ̀sán ni òkùnkùn ti bo gbogbo ilẹ̀ títí di agogo mẹta ọ̀sán. Nígbà tí ó tó nǹkan bí agogo mẹta ọ̀sán, Jesu kígbe ní ohùn rara pé, “Eli, Eli, lema sabakitani?” Ìtumọ̀ èyí ni, “Ọlọrun mi! Ọlọrun mi! Kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?” Nígbà tí àwọn kan tí ó dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n ní, “Ọkunrin yìí ń pe Elija.” Lẹsẹkẹsẹ ọ̀kan ninu wọn sáré, ó ti nǹkankan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi sórí ọ̀pá láti fi fún un mu. Ṣugbọn àwọn yòókù ń sọ pé, “Fi í sílẹ̀! Jẹ́ kí a wò bí Elija yóo wá gbà á là.” Jesu bá tún kígbe tòò, ó mí kanlẹ̀, ó bá dákẹ́. Aṣọ ìkélé tí ó wà ninu Tẹmpili ya sí meji láti òkè dé ilẹ̀. Ilẹ̀ mì tìtì. Àwọn òkè sán. Òkúta ẹnu ibojì ṣí, a sì jí ọ̀pọ̀ òkú àwọn olódodo dìde. Wọ́n jáde kúrò ninu ibojì lẹ́yìn tí Jesu ti jí dìde, wọ́n wọ Jerusalẹmu lọ, ọpọlọpọ eniyan ni ó rí wọn. Nígbà tí ọ̀gágun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ tí wọn ń ṣọ́ Jesu rí ilẹ̀ tí ó mì ati gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Wọ́n ní, “Nítòótọ́ Ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.” Ọ̀pọ̀ àwọn obinrin wà níbẹ̀ tí wọ́n dúró ní òkèèrè réré, tí wọn ń wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Àwọn ni wọ́n tí ń tẹ̀lé Jesu láti Galili, tí wọn ń ṣe iranṣẹ fún un. Maria Magidaleni wà lára wọn, ati Maria ìyá Jakọbu ati ti Josẹfu ati ìyá àwọn ọmọ Sebede.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú MATIU 27:45-56