MATIU 26:36-45

MATIU 26:36-45 YCE

Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibìkan tí ó ń jẹ́ Gẹtisemani. Ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín, èmi ń lọ gbadura lọ́hùn-ún nì.” Ó bá mú Peteru ati àwọn ọmọ Sebede mejeeji lọ́wọ́, inú rẹ̀ bàjẹ́, ó sì dààmú. Ó wá sọ fún wọn pé, “Mo ní ìbànújẹ́ ọkàn tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ kú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ máa bá mi ṣọ́nà.” Ó wá tún lọ siwaju díẹ̀ síi, ó dojúbolẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura pé, “Baba mi, bí ó bá ṣeéṣe, mú kí ife kíkorò yìí fò mí ru. Ṣugbọn kì í ṣe ohun tí mo fẹ́ ni ṣíṣe, bíkòṣe ohun tí ìwọ fẹ́.” Ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá wọn tí wọn ń sùn. Ó sọ fún Peteru pé, “Èyí ni pé ẹ kò lè bá mi ṣọ́nà fún wakati kan? Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò. Ẹ̀mí fẹ́ ṣe é, ṣugbọn ara kò lágbára.” Ó tún lọ gbadura lẹẹkeji. Ó ní, “Baba mi, bí kò bá ṣeéṣe pé kí ife kíkorò yìí fò mí ru, tí ó jẹ́ ohun tí ó níláti ṣẹlẹ̀ sí mi, ìfẹ́ tìrẹ ni ṣíṣe.” Ó tún wá, ó tún bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí wọn ń sùn, nítorí oorun ń kùn wọ́n pupọ. Ó bá fi wọ́n sílẹ̀, ó pada lọ gbadura ní ẹẹkẹta; ó tún sọ nǹkankan náà. Lẹ́yìn náà ó wá lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ tún wà níbi tí ẹ̀ ń sùn, tí ẹ̀ ń sinmi! Ẹ wò ó! Àkókò náà súnmọ́ tòsí tí a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú MATIU 26:36-45