MATIU 23:13-39

MATIU 23:13-39 YCE

“Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin alárèékérekè wọnyi. Nítorí ẹ ti ìlẹ̀kùn ìjọba ọ̀run mọ́ àwọn eniyan, ẹ̀yin fúnra yín kò wọlé, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí wọ́n fẹ́ wọlé, ẹ kò jẹ́ kí wọ́n wọlé. [ “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati Farisi, alaiṣootọ; nítorí ẹ̀ ń jẹ ilé àwọn opó run; ẹ̀ ń fi adura gígùn ṣe ìbòjú. Nítorí èyí, ẹ óo gba ìdálẹ́bi pupọ.”] “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn, nítorí ẹ̀ ń la òkun ati oríṣìíríṣìí ìlú kọjá láti mú ẹyọ ẹnìkan láti orílẹ̀-èdè mìíràn wọ ẹ̀sìn yín. Nígbà tí ó bá ti wọ ẹ̀sìn tán, ẹ wá sọ ọ́ di ẹni ọ̀run àpáàdì ní ìlọ́po meji ju ẹ̀yin alára lọ. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin afọ́jú tí ń fọ̀nà han eniyan. Ẹ̀ ń sọ pé, ‘Bí eniyan bá fi Tẹmpili búra, kò ṣe nǹkankan. Ṣugbọn bí eniyan bá fi wúrà tí ó wà ninu Tẹmpili búra, olúwarẹ̀ níláti mú ìbúra rẹ̀ ṣẹ.’ Ẹ̀yin afọ́jú òmùgọ̀ wọnyi! Èwo ni ó ṣe pataki jù! Wúrà ni tabi Tẹmpili tí a fi sọ wúrà di ohun ìyàsọ́tọ̀? Ẹ tún sọ pé, ‘Bí eniyan bá fi pẹpẹ ìrúbọ búra, kò ṣe nǹkankan. Ṣugbọn bí eniyan bá fi ọrẹ tí ó wà lórí pẹpẹ ìrúbọ búra, olúwarẹ̀ níláti mú ìbúra rẹ̀ ṣẹ.’ Ẹ̀yin afọ́jú wọnyi! Èwo ni ó ṣe pataki jù, ọrẹ ni, tabi pẹpẹ ìrúbọ tí ó sọ ọ́ di ohun ìyàsọ́tọ̀? Nítorí náà ẹni tí ó bá fi pẹpẹ ìrúbọ búra, ati pẹpẹ ati ohun gbogbo tí ó wà lórí rẹ̀ ni ó fi búra. Ẹni tí ó bá fi Tẹmpili búra, ohun tí ó wà ninu rẹ̀ ati Ọlọrun tí ó ń gbé inú rẹ̀ ni ó fi búra pẹlu. Ẹni tí ó bá fi ọ̀run búra, ó fi ìtẹ́ Ọlọrun ati Ọlọrun tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà búra pẹlu. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn wọnyi! Ẹ̀ ń san ìdámẹ́wàá àwọn èròjà ọbẹ̀ tí wọ́n jẹ́ eléwé, nígbà tí ẹ gbàgbé àwọn ohun tí ó ṣe pataki ninu òfin: bíi ìdájọ́ òdodo, àánú, ati igbagbọ. Àwọn ohun tí ẹ̀ bá mójútó nìyí, láì gbàgbé ìdámẹ́wàá. Ẹ̀yin afọ́jú tí ń fọ̀nà han eniyan! Ẹ̀ ń yọ kòkòrò tín-tìn-tín kúrò ninu ohun tí ẹ̀ ń mu, ṣugbọn ẹ̀ ń gbé ràkúnmí mì mọ́ omi yín! “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn. Ẹ̀ ń fọ òde ife ati òde àwo oúnjẹ nígbà tí inú wọn kún fún àwọn ohun tí ẹ fi ìwà olè ati ìwà ìmọ-tara-ẹni-nìkan já gbà. Ìwọ afọ́jú Farisi! Kọ́kọ́ fọ inú ife ná, òde rẹ̀ náà yóo sì mọ́. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn wọnyi. Ẹ dàbí àwọn ibojì tí a kùn ní funfun, tí ó dùn-ún wò lóde, ṣugbọn inú wọn kún fún egungun òkú ati oríṣìíríṣìí ohun ẹ̀gbin. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ẹ̀yin náà rí lóde, lójú àwọn eniyan ẹ dàbí ẹni rere, ṣugbọn ẹ kún fún àṣehàn ati ìwà burúkú. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn wọnyi. Ẹ̀ ń ṣe ibojì fún àwọn wolii, ẹ sì ń ṣe ibojì àwọn eniyan rere lọ́ṣọ̀ọ́. Ẹ wá ń sọ pé, ‘Bí ó bá jẹ́ pé a wà ní ìgbà àwọn baba wa, àwa kò bá tí lọ́wọ́ ninu ikú àwọn wolii.’ Nípa gbolohun yìí, ẹ̀ ń jẹ́rìí sí ara yín pé ọmọ àwọn tí ó pa àwọn wolii ni yín. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin náà ẹ múra, kí ẹ parí ohun tí àwọn baba yín ṣe kù! Ẹ̀yin ejò, ìran paramọ́lẹ̀! Báwo ni ẹ kò ti ṣe ní gba ìdájọ́ ọ̀run àpáàdì? Nítorí èyí ni mo fi rán àwọn wolii, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ati àwọn amòfin si yín. Ẹ óo pa òmíràn ninu wọn, ẹ óo sì kan òmíràn mọ́ agbelebu. Ẹ óo na àwọn mìíràn ninu wọn ní ilé ìpàdé yín, ẹ óo sì máa lépa wọn láti ìlú dé ìlú. Ẹ óo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi kí ẹ lè fi orí gba ẹ̀bi ikú gbogbo eniyan rere tí ẹ ti ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀; ohun tí ó ṣẹ̀ láti orí Abeli, ẹni rere títí fi dé orí Sakaraya, ọmọ Berekaya, tí ẹ pa láàrin àgọ́ mímọ́ ati pẹpẹ ìrúbọ. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ìran yìí ni yóo fi orí fá gbogbo ẹ̀bi yìí. “Jerusalẹmu! Jerusalẹmu! Ìwọ tí ò ń pa àwọn wolii, tí ò ń sọ àwọn tí a rán sí ọ ní òkúta pa! Ìgbà mélòó ni mo ti fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ, bí adìẹ tí ń kó àwọn ọmọ rẹ̀ sí abẹ́! Ṣugbọn o kọ̀ fún mi. Wò ó, a óo sọ Tẹmpili rẹ di ahoro. Nítorí náà, mo sọ fun yín pé ẹ kò ní fojú kàn mí mọ́ títí di àkókò tí ẹ óo wí pé, ‘Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Oluwa!’ ”

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ