Nígbà kan, ẹnìkan wá sọ́dọ̀ Jesu, ó bi í pé, “Olùkọ́ni, nǹkan rere wo ni kí n ṣe kí n lè ní ìyè ainipẹkun?” Jesu sọ fún un pé, “Nítorí kí ni o ṣe ń bi mí nípa ohun rere? Ẹni rere kanṣoṣo ni ó wà. Bí o bá fẹ́ wọ inú ìyè, pa àwọn òfin mọ́.” Ó bi Jesu pé, “Òfin bí irú èwo?” Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ pa eniyan. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè. Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè. Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké. Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ. Ati pé, fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.” Ọdọmọkunrin náà sọ fún Jesu pé, “Gbogbo òfin wọnyi ni mo ti pamọ́. Kí ni ó tún kù kí n ṣe?” Jesu sọ fún un pé, “Bí o bá fẹ́ ṣe àṣepé, lọ ta dúkìá rẹ, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka; o óo sì ní ìṣúra ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, máa tẹ̀lé mi.”
Kà MATIU 19
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MATIU 19:16-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò