Lẹ́yìn tí wọn kó wọn lẹ́rú lọ sí Babiloni, Jekonaya bí Ṣealitieli, Ṣealitieli bí Serubabeli. Serubabeli bí Abihudi, Abihudi bí Eliakimu, Eliakimu bí Asori. Asori bí Sadoku, Sadoku bí Akimu, Akimu bí Eliudi. Eliudi bí Eleasari, Eleasari bí Matani, Matani bí Jakọbu. Jakọbu bí Josẹfu ọkọ Maria, ẹni tí ó bí Jesu tí à ń pè ní Kristi.
Kà MATIU 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MATIU 1:12-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò