Ó tó bí ọjọ́ mẹjọ lẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀, Jesu mú Peteru, Johanu ati Jakọbu lọ sí orí òkè kan láti gbadura. Bí ó ti ń gbadura, ìwò ojú rẹ̀ yipada, aṣọ rẹ̀ wá funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Àwọn ọkunrin meji kan yọ lójijì, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀. Àwọn ni Mose ati Elija. Wọ́n farahàn ninu ògo, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀ nípa irú ikú tí yóo kú láìpẹ́, ní Jerusalẹmu. Ṣugbọn oorun ti ń kun Peteru ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀. Nígbà tí wọ́n tají, wọ́n rí ògo rẹ̀ ati àwọn ọkunrin meji tí wọ́n dúró tì í. Bí àwọn meji yìí ti ń kúrò lọ́dọ̀ Jesu, Peteru sọ fún un pé, “Ọ̀gá, ìbá dára tí a bá lè máa wà níhìn-ín. Jẹ́ kí á pa àgọ́ mẹta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose, ati ọ̀kan fún Elija.” Ó sọ èyí nítorí kò mọ ohun tíì bá sọ.
Bí ó ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, ìkùukùu bá ṣíji bò wọ́n. Ẹ̀rù ba Peteru ati Johanu ati Jakọbu nígbà tí Mose ati Elija wọ inú ìkùukùu náà. Ohùn kan ti inú ìkùukùu náà wá, ó ní “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀!”
Bí wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, Jesu nìkan ni wọ́n rí. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá pa ẹnu mọ̀, wọn kò sọ ohun tí wọ́n gbọ́ ati ohun tí wọ́n rí ní àkókò náà fún ẹnikẹ́ni.
Ní ọjọ́ keji, lẹ́yìn tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ọ̀pọ̀ eniyan wá pàdé rẹ̀. Ọkunrin kan ninu àwùjọ kígbe pé, “Olùkọ́ni, mo bẹ̀ ọ́, ṣàánú ọmọ mi, nítorí òun nìkan ni mo bí. Ẹ̀mí kan a máa gbé e. Lójijì yóo kígbe tòò, ara rẹ̀ óo le gbandi. Yóo bá máa yọ ìfòòfó lẹ́nu, ni ẹ̀mí yìí yóo bá gbé e ṣánlẹ̀; kò sì ní tètè fi í sílẹ̀. Mo bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pé kí wọ́n lé e jáde, ṣugbọn wọn kò lè ṣe é.”
Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin ìran oníbàjẹ́ ati alaigbagbọ yìí! N óo ti wà pẹlu yín pẹ́ tó! N óo ti fara dà á fun yín tó! Mú ọmọ rẹ wá síhìn-ín.”
Bí ó ti ń mú un bọ̀, ẹ̀mí èṣù yìí bá gbé e ṣánlẹ̀, wárápá bá mú un. Jesu bá bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó wo ọmọ náà sàn, ó bá fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́. Ẹnu ya gbogbo eniyan sí iṣẹ́ ńlá Ọlọrun.
Bí ẹnu ti ń ya gbogbo eniyan sí gbogbo ohun tí Jesu ń ṣe, ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi wọ̀ yín létí. Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò tí a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan lọ́wọ́.” Ṣugbọn gbolohun yìí kò yé wọn, nítorí a ti fi ìtumọ̀ rẹ̀ pamọ́ fún wọn, kí ó má baà yé wọn. Ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bi í nípa ọ̀rọ̀ yìí.
Àríyànjiyàn kan bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lórí pé ta ló ṣe pataki jùlọ láàrin wọn. Jesu mọ ohun tí wọn ń rò lọ́kàn. Ó bá mú ọmọde kan, ó gbé e dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọde yìí ní orúkọ mi, èmi ni ó gbà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mí, gba ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi. Nítorí ẹni tí ó kéré jùlọ ninu yín, òun ló jẹ́ eniyan pataki jùlọ.”