LUKU 16:1-13

LUKU 16:1-13 YCE

Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà tí ó ní ọmọ-ọ̀dọ̀ kan. Wọ́n fi ẹ̀sùn kan ọmọ-ọ̀dọ̀ yìí pé ó ń fi nǹkan ọ̀gá rẹ̀ ṣòfò. Ọ̀gá rẹ̀ bá pè é, ó sọ fún un pé, ‘Irú ìròyìn wo ni mò ń gbọ́ nípa rẹ yìí? Ṣírò iṣẹ́ rẹ bí ọmọ-ọ̀dọ̀, nítorí n óo dá ọ dúró lẹ́nu iṣẹ́.’ Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà wá rò ninu ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni n óo ṣe o, nítorí ọ̀gá mi yóo dá mi dúró lẹ́nu iṣẹ́. Èmi nìyí, n kò lè roko. Ojú sì ń tì mí láti máa ṣagbe. Mo mọ ohun tí n óo ṣe, kí àwọn eniyan lè gbà mí sinu ilé wọn nígbà tí wọ́n bá gba iṣẹ́ lọ́wọ́ mi.’ “Ó bá pe ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn tí ó jẹ ọ̀gá rẹ̀ ní gbèsè. Ó bi ekinni pé, ‘Èló ni o jẹ ọ̀gá mi?’ Òun bá dáhùn pé, ‘Ọgọrun-un garawa epo.’ Ó sọ fún un pé, ‘Gba ìwé àkọsílẹ̀ rẹ, tètè jókòó, kọ aadọta.’ Ó bi ekeji pé, ‘Ìwọ ńkọ́? Èló ni o jẹ?’ Ó ní, ‘Ẹgbẹrun òṣùnwọ̀n àgbàdo.’ Ó sọ fún un pé, ‘Gba ìwé àkọsílẹ̀ rẹ, kọ ẹgbẹrin.’ “Ọ̀gá ọmọ-ọ̀dọ̀ ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ náà yìn ín nítorí pé ó gbọ́n. Nítorí àwọn ọmọ ayé yìí mọ ọ̀nà ọgbọ́n tí wọ́n fi ń bá ara wọn lò ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ. “Ní tèmi, mò ń sọ fun yín, fún anfaani ara yín, ẹ fi ọrọ̀ ayé yìí wá ọ̀rẹ́ fún ara yín, tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí owó kò bá sí mọ́, kí wọn lè gbà yín sí inú ibùgbé tí yóo wà títí lae. Ẹni tí ó bá ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré yóo ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan ńlá. Nítorí náà bí ẹ kò bá ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nípa nǹkan owó ti ayé yìí, ta ni yóo fi dúkìá tòótọ́ sí ìkáwọ́ yín? Bí ẹ kò bá ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nípa ohun tí ó jẹ́ ti ẹlòmíràn, ta ni yóo fun yín ní ohun tí ó jẹ́ ti ẹ̀yin fúnra yín? “Kò sí ọmọ-ọ̀dọ̀ kan tí ó lè sin oluwa meji. Nítorí ọ̀kan ni yóo ṣe: ninu kí ó kórìíra ọ̀kan, kí ó fẹ́ràn ekeji, tabi kí ó fara mọ́ ọ̀kan, kí ó má sì ka ekeji sí. Ẹ kò lè sin Ọlọrun, kí ẹ tún sin owó.”