LUKU 12:1-21

LUKU 12:1-21 YCE

Ní àkókò yìí, ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ; wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn fi ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀. Jesu kọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ná. Ó ní, “Ẹ ṣọ́ ara yín nípa ìwúkàrà àwọn Farisi, àwọn alágàbàgebè. Ṣugbọn kò sí ohun kan tí a fi aṣọ bò tí a kò ní ṣí aṣọ lórí rẹ̀. Kò sì sí ohun àṣírí tí eniyan kò ní mọ̀. Kí ẹ mọ̀ pé ohunkohun tí ẹ sọ ní ìkọ̀kọ̀, a óo gbọ́ nípa rẹ̀ ní gbangba. Ohun tí ẹ bá sọ ninu yàrá, lórí òrùlé ni a óo ti pariwo rẹ̀. “Mò ń sọ fun yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, pé kí ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọ́n lè pa ara, tí kò tún sí ohun tí wọ́n le ṣe mọ́ lẹ́yìn rẹ̀! N óo fi ẹni tí ẹ̀ bá bẹ̀rù hàn yín. Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó jẹ́ pé nígbà tí ó bá pa ara tán, ó ní àṣẹ láti tún sọ eniyan sinu ọ̀run àpáàdì. Mo sọ fun yín, ẹ bẹ̀rù olúwarẹ̀. “Mo ṣebí kọbọ meji ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́ marun-un. Sibẹ kò sí ọ̀kan ninu wọn tí Ọlọrun fi ojú fò dá. Àní sẹ́, gbogbo irun orí yín ni ó níye. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ níye lórí pupọ ju ológoṣẹ́ lọ. “Mo sọ fun yín, gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú eniyan, Ọmọ-Eniyan yóo jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú àwọn angẹli Ọlọrun. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sẹ́ mi níwájú eniyan ni a óo sẹ́ níwájú àwọn angẹli Ọlọrun. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ kan lòdì sí Ọmọ-Eniyan, a óo dáríjì í. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ẹ̀mí Mímọ́, a kò ní dáríjì í. “Nígbà tí wọ́n bá mu yín lọ sinu ilé ìpàdé ati siwaju àwọn ìjòyè ati àwọn aláṣẹ, ẹ má ṣe dààmú nípa bí ẹ óo ti ṣe wí àwíjàre tabi pé kí ni ẹ óo sọ. Nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ yóo kọ yín ní ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ ní àkókò náà.” Ẹnìkan ninu àwọn eniyan sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, sọ fún arakunrin mi kí ó fún mi ní ogún tí ó kàn mí.” Jesu dá a lóhùn pé, “Arakunrin, ta ni ó yàn mí ní onídàájọ́ tabi ẹni tí ń pín ogún kiri?” Jesu wá sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ ṣọ́ra, ẹ ta kété sí ojúkòkòrò ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà, nítorí ọ̀pọ̀ dúkìá nìkan kọ́ níí sọni di eniyan.” Jesu bá pa òwe kan fún wọn. Ó ní, “Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà tí ìkórè oko rẹ̀ pọ̀ pupọ. Ó wá ń rò ninu ọkàn rẹ̀ pé, ‘Kí ni ǹ bá ṣe o, nítorí n kò rí ibi kó ìkórè oko mi pamọ́ sí?’ Ó ní, ‘Mo mọ ohun tí n óo ṣe! Ńṣe ni n óo wó àwọn abà mi. N óo wá kọ́ àwọn ńláńlá mìíràn; níbẹ̀ ni n óo kó àgbàdo mi sí ati àwọn ìkórè yòókù. N óo wá sọ fún ọkàn mi pé: ọkàn mi, o ní ọ̀pọ̀ irè-oko tí ó wà ní ìpamọ́ fún ọdún pupọ. Ìdẹ̀ra dé. Máa jẹ, máa mu, máa gbádùn!’ Ṣugbọn Ọlọrun wí fún un pé, ‘Ìwọ aṣiwèrè yìí! Ní alẹ́ yìí ni a óo gba ẹ̀mí rẹ pada lọ́wọ́ rẹ. Ta ni yóo wá jogún gbogbo ohun tí o kó jọ wọnyi?’ “Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ẹni tí ó to ìṣúra jọ fún ara rẹ̀, tí kò ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun.”