Sakaraya, baba ọmọ náà, kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ó bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, Kí á yin Oluwa Ọlọrun Israẹli nítorí ó ti mú ìrànlọ́wọ́ wá fún àwọn eniyan rẹ̀, ó sì ti dá wọn nídè. Ó ti gbé Olùgbàlà dìde fún wa ní ìdílé Dafidi, iranṣẹ rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀ mímọ́, láti ọjọ́ pípẹ́; pé yóo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa ati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ó kórìíra wa; pé yóo fi àánú bá àwọn baba wa lò, ati pé yóo ranti majẹmu rẹ̀ mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún Abrahamu baba wa, pé yóo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, ati pé yóo fún wa ní anfaani láti máa sìn ín láì fòyà, pẹlu ọkàn kan ati pẹlu òdodo níwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. “Ìwọ, ọmọ mi, wolii Ọ̀gá Ògo ni a óo máa pè ọ́, nítorí ìwọ ni yóo ṣáájú Oluwa láti palẹ̀ mọ́ dè é, láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn eniyan rẹ̀, nípa ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí àánú Ọlọrun wa, nípa èyí tí oòrùn ìgbàlà fi ràn lé wa lórí láti òkè wá, láti tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn tí ó wà ní òkùnkùn ati àwọn tí ó jókòó níbi òjìji ikú, láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà alaafia.”
Kà LUKU 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: LUKU 1:67-79
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò