Èmi Juda, iranṣẹ Jesu Kristi, tí mo jẹ́ arakunrin Jakọbu ni mò ń kọ ìwé yìí sí àwọn tí Ọlọrun Baba fẹ́ràn, tí Jesu Kristi pè láti pamọ́.
Kí àánú, alaafia ati ìfẹ́ kí ó máa pọ̀ sí i fun yín.
Ẹ̀yin olùfẹ́, mo ti gbìyànjú títí láti kọ ìwé si yín nípa ìgbàlà tí a jọ ní, nígbà tí mo rí i pé ó di dandan pé kí n kọ ìwé si yín, kí n rọ̀ yín pé kí ẹ máa jà fún igbagbọ tí Ọlọrun fi fún àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ lẹ́ẹ̀kan gbọ̀n-ọ́n. Nítorí àwọn kan ti yọ́ wọ inú ìjọ, àwọn tí Ìwé Mímọ́ ti sọ nípa wọn lọ́jọ́ tó ti pẹ́ pé ìdájọ́ ń bọ̀ sórí wọn. Wọ́n jẹ́ aláìbọ̀wọ̀ fún Ọlọrun, wọ́n yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wa pada sí àìdára láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ inú wọn, wọ́n sẹ́ Ọ̀gá wa kanṣoṣo ati Oluwa wa Jesu Kristi.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti mọ gbogbo nǹkan wọnyi, sibẹ mo fẹ́ ran yín létí pé lẹ́yìn tí Oluwa ti gba àwọn eniyan là kúrò ní ilẹ̀ Ijipti tán, nígbà tí ó yá, ó tún pa àwọn tí kò gbàgbọ́ run. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn angẹli tí wọn kọjá ààyè wọn àkọ́kọ́, tí wọ́n kúrò ní ipò tí Ọlọrun kọ́ fi wọ́n sí. Ẹ̀wọ̀n ayérayé ni Ọlọrun fi dè wọ́n mọ́ inú òkùnkùn biribiri títí di ọjọ́ ńlá nnì tíí ṣe ọjọ́ ìdájọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìlú Sodomu ati ìlú Gomora ati àwọn ìlú tí ó yí wọn ká. Àwọn náà ṣe bí àwọn angẹli tí wọ́n kọjá ààyè wọn, wọ́n ṣe àgbèrè ati oríṣìíríṣìí ohun ìbàjẹ́ tí kò bá ìwà eniyan mu. Ọlọrun fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún gbogbo eniyan nígbà tí wọ́n jìyà iná ajónirun.
Bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí fún àwọn eniyan wọnyi lónìí. Àlá tí wọn ń lá, fún ìbàjẹ́ ara wọn ni. Wọ́n tàpá sí àwọn aláṣẹ. Wọ́n ń sọ ìsọkúsọ sí àwọn ẹ̀dá ọ̀run tí ó lógo. Nígbà tí Mikaeli, olórí àwọn angẹli pàápàá ń bá Èṣù jiyàn, tí wọ́n ń jìjàdù òkú Mose, kò tó sọ ìsọkúsọ sí i. Ohun tí ó sọ ni pé, “Oluwa yóo bá ọ wí.” Ṣugbọn àwọn eniyan wọnyi a máa sọ ìsọkúsọ nípa ohunkohun tí kò bá ti yé wọn. Àwọn nǹkan tí ó bá sì yé wọn, bí nǹkan tíí yé ẹranko ni. Ohun tí ń mú ìparun bá wọn nìyí. Ó ṣe fún wọn! Wọ́n ń rìn ní ọ̀nà Kaini. Wọ́n tẹra mọ́ ọ̀nà ẹ̀tàn Balaamu nítorí ohun tí wọn yóo rí gbà. Wọ́n dá ọ̀tẹ̀ sílẹ̀ bíi Kora, wọ́n sì parun. Bàsèjẹ́ ni wọ́n jẹ́ ninu àsè ìfẹ́ ìjọ, wọn kò ní ọ̀wọ̀ nígbà tí ẹ bá jọ ń jẹ, tí ẹ jọ ń mu. Ara wọn nìkan ni wọ́n ń tọ́jú bí olùṣọ́-aguntan tí ń tọ́jú ara rẹ̀ dípò aguntan. Wọ́n dàbí ìkùukùu tí afẹ́fẹ́ ń gbá kiri tí kò rọ òjò. Igi tí kò ní èso ní àkókò ìkórè ni wọ́n, wọ́n ti kú sára. Nígbà tí ó bá ṣe, wọn á wó lulẹ̀ tigbòǹgbò-tigbòǹgbò. Ìgbì omi òkun líle ni wọ́n, tí ó ń rú ìwà ìtìjú wọn jáde. Ìràwọ̀ tí kò gbébìkan ni wọ́n. Ààyè wọn ti wà nílẹ̀ fún wọn, ninu òkùnkùn biribiri títí ayé ainipẹkun.
Nípa àwọn wọnyi ni Enọku tí ó jẹ́ ìran keje sí Adamu sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, “Mo rí Oluwa tí ó dé pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun àwọn angẹli rẹ̀ mímọ́, láti ṣe ìdájọ́ lórí gbogbo ẹ̀dá. Yóo bá gbogbo àwọn eniyan burúkú wí fún gbogbo ìwà burúkú tí wọ́n ti hù, ati gbogbo ọ̀rọ̀ líle tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bẹ̀rù Ọlọrun ti sọ sí òun Oluwa.”
Àwọn wọnyi ni àwọn tí wọn ń kùn ṣá, nǹkan kì í fi ìgbà kan tẹ́ wọn lọ́rùn. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn ni wọ́n ń lépa. Ẹnu wọn gba ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà. Kò sí ohun tí wọn kò lè ṣe láti rí ohun tí wọ́n fẹ́. Wọn á máa wá ojú rere àwọn tí wọ́n bá lè rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn.
Ṣugbọn ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, ẹ̀yin ẹ ranti ohun tí Oluwa wa Jesu Kristi ti ti ẹnu àwọn aposteli rẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀. Wọ́n kìlọ̀ fun yín pé ní àkókò ìkẹyìn, àwọn kan yóo máa fi ẹ̀sìn ṣe ẹlẹ́yà, wọn yóo máa tẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn láì bẹ̀rù Ọlọrun. Àwọn wọnyi ni wọ́n ń ya ara wọn sọ́tọ̀. Wọ́n hùwà bí ẹranko, wọn kò ní Ẹ̀mí Mímọ́. Ṣugbọn ẹ̀yin, àyànfẹ́ mi, ẹ fi igbagbọ yín tí ó mọ́ jùlọ ṣe odi fún ara yín, kí ẹ máa gbadura nípa agbára tí ó wà ninu Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ pa ara yín mọ́ ninu ìfẹ́ Ọlọrun. Ẹ máa retí ìyè ainipẹkun tí Oluwa wa Jesu Kristi yóo fun yín ninu àánú rẹ̀.
Ẹ máa ṣàánú àwọn tí ó ń ṣiyèméjì. Inú iná ni ẹ ti níláti yọ àwọn mìíràn kí ẹ tó lè gbà wọ́n là. Ìbẹ̀rù-bojo ni kí ẹ fi máa ṣàánú àwọn mìíràn. Ẹ níláti kórìíra aṣọ tí ìfẹ́ ara ti da àbààwọ́n sí.
Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó lè pa yín mọ́ tí ẹ kò fi ní ṣubú, tí ó lè mu yín dúró pẹlu ayọ̀ níwájú ògo rẹ̀ láì lábàwọ́n, Ọlọrun nìkan ṣoṣo, Olùgbàlà wa nípasẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa ni ògo, ọlá, agbára ati àṣẹ wà fún, kí á tó dá ayé, ati nisinsinyii ati títí ayé ainipẹkun. Amin.