Joṣua bá to àwọn òkúta mejila tí wọ́n kó jáde láti inú odò Jọdani kalẹ̀ ní Giligali. Ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá bèèrè lọ́wọ́ àwọn baba wọn ní ọjọ́ iwájú pé báwo ni ti àwọn òkúta wọnyi ti jẹ́ rí? Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀ pé àwọn ọmọ Israẹli kọjá odò Jọdani yìí lórí ilẹ̀ gbígbẹ. Nítorí OLUWA Ọlọrun yín mú kí odò Jọdani gbẹ títí ẹ fi rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti mú kí Òkun Pupa gbẹ, títí tí ẹ fi là á kọjá. Kí gbogbo aráyé lè mọ̀ pé, OLUWA lágbára, kí ẹ sì lè máa bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín títí lae.”
Kà JOṢUA 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOṢUA 4:20-24
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò