Bí Jesu ti ń kọjá lọ, ó rí ọkunrin kan tí ó fọ́jú láti inú ìyá rẹ̀ wá. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í pé, “Olùkọ́ni, ta ni ó dẹ́ṣẹ̀, ọkunrin yìí ni, tabi àwọn òbí rẹ̀, tí wọ́n fi bí i ní afọ́jú?” Jesu dáhùn pé, “Ati òun ni, ati àwọn òbí rẹ̀ ni, kò sí ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn kí iṣẹ́ Ọlọrun lè hàn nípa ìwòsàn rẹ̀ ni. Dandan ni fún mi kí n ṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi ní ojúmọmọ, ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ ṣú ná, tí ẹnikẹ́ni kò ní lè ṣiṣẹ́. Níwọ̀n ìgbà tí mo wà ní ayé, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó tutọ́ sílẹ̀, ó fi po amọ̀, ó bá fi lẹ ojú ọkunrin náà. Ó wí fún un pé, “Lọ bọ́jú ninu adágún tí ó ń jẹ́ Siloamu.” (Ìtumọ̀ Siloamu ni “rán níṣẹ́.”) Ọkunrin náà lọ, ó bọ́jú, ó bá ríran.
Kà JOHANU 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOHANU 9:1-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò