Jesu tún lọ sí ìlú Kana ti Galili níbi tí ó ti sọ omi di ọtí ní ìjelòó. Ìjòyè kan wà ní Kapanaumu tí ọmọ rẹ̀ ń ṣàìsàn. Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti dé sí Galili láti Judia, ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá wo ọmọ òun sàn, nítorí ọmọ ọ̀hún ń kú lọ. Jesu wí fún un pé, “Bí ẹ kò bá rí iṣẹ́ àmì ati iṣẹ́ ìyanu ẹ kò ní gbàgbọ́.” Ìjòyè náà bẹ̀ ẹ́ pé, “Alàgbà, tètè wá kí ọmọ mi tó kú.” Jesu wí fún un pé, “Máa lọ, ọmọ rẹ yóo yè.” Ọkunrin náà gba ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ fún un gbọ́, ó bá ń lọ sílé. Bí ó ti ń lọ, àwọn iranṣẹ rẹ̀ wá pàdé rẹ̀, wọ́n wí fún un pé, “Ọmọ rẹ ti gbádùn.” Ìjòyè náà wádìí lọ́wọ́ wọn nípa àkókò tí ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Lánàá, ní nǹkan bí aago kan ni ibà náà lọ.” Baba ọmọ náà mọ̀ pé àkókò náà gan-an ni Jesu sọ fún òun pé, “Ọmọ rẹ yóo yè.” Òun ati gbogbo ilé rẹ̀ bá gba Jesu gbọ́.
Kà JOHANU 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOHANU 4:46-53
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò