JOHANU 21:15-20

JOHANU 21:15-20 YCE

Nígbà tí wọ́n jẹun tán, Jesu bi Simoni Peteru pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi ju àwọn wọnyi lọ?” Peteru dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn ọ̀dọ́ aguntan mi.” Jesu tún bi í lẹẹkeji pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó tún dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu wí fún un pé, “Máa tọ́jú àwọn aguntan mi.” Jesu tún bi í ní ẹẹkẹta pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó dun Peteru nítorí Jesu bi í ní ẹẹkẹta pé, “Ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó wá sọ fún Jesu pé, “Oluwa, o mọ ohun gbogbo, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu sọ fún un pé, “Máa bọ́ àwọn aguntan mi. Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé nígbà tí o wà ní ọ̀dọ́, ò ń di ara rẹ ni àmùrè gírí, ò ń lọ sí ibi tí o bá fẹ́. Ṣugbọn nígbà tí o bá di arúgbó, ìwọ yóo na ọwọ́ rẹ, ẹlòmíràn yóo wọ aṣọ fún ọ, yóo fà ọ́ lọ sí ibi tí o kò fẹ́ lọ.” (Jesu sọ èyí bí àkàwé irú ikú tí Peteru yóo fi yin Ọlọrun lógo.) Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ó wí fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Nígbà tí Peteru bojú wẹ̀yìn, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn tí ó ń tẹ̀lé e. Òun ni ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí nígbà tí wọn ń jẹun, tí ó bi Jesu pé, “Oluwa, ta ni yóo fi ọ́ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ rí?”