Ṣugbọn Maria dúró lóde lẹ́bàá ibojì, ó ń sunkún. Bí ó ti ń sunkún, ó bẹ̀rẹ̀ ó yọjú wo inú ibojì, ó bá rí àwọn angẹli meji tí wọ́n wọ aṣọ funfun, ọ̀kan jókòó níbi orí, ekeji jókòó níbi ẹsẹ̀ ibi tí wọ́n tẹ́ òkú Jesu sí. Wọ́n bi í pé, “Obinrin, kí ló dé tí ò ń sunkún?”
Ó dá wọn lóhùn pé, “Wọ́n ti gbé Oluwa mi lọ, n kò mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.”
Bí ó ti sọ báyìí tán, ó bojú wẹ̀yìn, ó bá rí Jesu tí ó dúró, ṣugbọn kò mọ̀ pé òun ni. Jesu bi í pé, “Obinrin, kí ní dé tí ò ń sunkún? Ta ni ò ń wá?”
Maria ṣebí olùṣọ́gbà ni. Ó sọ fún un pé, “Alàgbà, bí o bá ti gbé e lọ, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, kí n lè lọ gbé e.”
Jesu bá pè é lórúkọ, ó ní, “Maria!”
Maria bá yipada sí i, ó pè é ní èdè Heberu pé, “Raboni!” (Ìtumọ̀ èyí ni “Olùkọ́ni.”)
Jesu bá sọ fún un pé, “Mú ọwọ́ kúrò lára mi, nítorí n kò ì tíì gòkè tọ Baba mi lọ. Ṣugbọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi, kí o sọ fún wọn pé, ‘Mò ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi ati Baba yín, Ọlọrun mi ati Ọlọrun yín.’ ”
Maria Magidaleni bá lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Mo ti rí Oluwa!” Ó bá sọ ohun tí Jesu sọ fún un fún wọn.
Nígbà tí ó di alẹ́ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, níbi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wà, tí wọ́n ti ìlẹ̀kùn mọ́rí nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu, Jesu dé, ó dúró láàrin wọn. Ó kí wọn pé, “Alaafia fun yín!” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó fi ọwọ́ rẹ̀ ati ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ hàn wọ́n. Ó tún kí wọn pé, “Alaafia fún yín! Gẹ́gẹ́ bí baba ti rán mi níṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni mo rán yín.” Lẹ́yìn tí ó sọ bẹ́ẹ̀ tán, ó mí sí wọn, ó bá wí fún wọn pé, “Ẹ gba Ẹ̀mí Mímọ́. Àwọn ẹni tí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì, Ọlọrun dáríjì wọ́n. Àwọn ẹni tí ẹ kò bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì, Ọlọrun kò dáríjì wọ́n.”
Ṣugbọn Tomasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila tí wọn ń pè ní Didimu (èyí ni “Ìbejì”) kò sí láàrin àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nígbà tí Jesu farahàn wọ́n. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù sọ fún un pé, “Àwa ti rí Oluwa!”
Ṣugbọn ó sọ fún wọn pé, “Bí n kò bá rí àpá ìṣó ní ọwọ́ rẹ̀, kí n fi ìka mi kan ibi tí àpá ìṣó wọ̀n-ọn-nì wà, kí n fi ọwọ́ mi kan ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, n kò ní gbàgbọ́!”
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹjọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tún wà ninu ilé, Tomasi náà wà láàrin wọn. Ìlẹ̀kùn wà ní títì bẹ́ẹ̀ ni Jesu bá tún dé, ó dúró láàrin wọn, ó ní, “Alaafia fun yín!” Ó wá wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá, wo ọwọ́ mi, mú ọwọ́ rẹ wá kí o fi kan ẹ̀gbẹ́ mi. Má ṣe alaigbagbọ mọ́, ṣugbọn gbàgbọ́.”
Tomasi dá a lóhùn pé, “Oluwa mi ati Ọlọrun mi!”
Jesu wí fún un pé, “O wá gbàgbọ́ nítorí o rí mi! Àwọn tí ó gbàgbọ́ láì rí mi ṣe oríire!”