JOHANU 16:16-24

JOHANU 16:16-24 YCE

“Láìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́. Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo sì tún rí mi.” Àwọn kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Kí ni ìtumọ̀ ohun tí ó wí fún wa yìí, ‘Láìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́. Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo sì tún rí mi?’ Kí tún ni ìtumọ̀, ‘Nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba?’ ” Wọ́n tún ń sọ pé, “Kí ni ìtumọ̀ ‘Láìpẹ́’ tí ó ń wí yìí? Ohun tí ó ń sọ kò yé wa.” Jesu mọ̀ pé wọ́n ń fẹ́ bi òun léèrè ọ̀rọ̀ yìí. Ó wá wí fún wọn pé, “Nítorí èyí ni ẹ ṣe ń bá ara yín jiyàn, nítorí mo sọ pé, ‘Laìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́,’ ati pé, ‘Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo tún rí mi?’ Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹ óo sunkún, ẹ óo ṣọ̀fọ̀, ṣugbọn inú aráyé yóo dùn. Ẹ óo dààmú ṣugbọn ìdààmú yín yóo di ayọ̀. Nígbà tí aboyún bá ń rọbí, ó gbọdọ̀ jẹ ìrora, nítorí àkókò ìkúnlẹ̀ rẹ̀ tó. Ṣugbọn nígbà tí ó bà bímọ tán, kò ní ranti gbogbo ìrora rẹ̀ mọ́, nítorí ayọ̀ pé ó bí ọmọ kan sinu ayé. Bákan náà ni: inú yín bàjẹ́ nisinsinyii, ṣugbọn n óo tún ri yín, inú yín yóo wá dùn, ẹnikẹ́ni kò ní lè mú ayọ̀ yín kúrò lọ́kàn yín. “Ní ọjọ́ náà, ẹ kò ní bi mí léèrè ohunkohun. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ohunkohun tí ẹ bá bèèrè lọ́dọ̀ Baba ní orúkọ mi, yóo fun yín. Ẹ kò ì tíì bèèrè ohunkohun ní orúkọ mi títí di ìsinsìnyìí. Ẹ bèèrè, ẹ óo sì rí gbà, kí ẹ lè ní ayọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.