JOHANU 11:18-46

JOHANU 11:18-46 YCE

Bẹtani kò jìnnà sí Jerusalẹmu, kò ju ibùsọ̀ meji lọ. Ọpọlọpọ ninu àwọn Juu ni wọ́n wá láti Jerusalẹmu sọ́dọ̀ Mata ati Maria láti tù wọ́n ninu nítorí ikú arakunrin wọn. Nígbà tí Mata gbọ́ pé Jesu ń bọ̀, ó jáde lọ pàdé rẹ̀. Ṣugbọn Maria jókòó ninu ilé. Mata sọ fún Jesu pé, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú! Ṣugbọn nisinsinyii náà, mo mọ̀ pé ohunkohun tí o bá bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun, yóo ṣe é fún ọ.” Jesu wí fún un pé, “Arakunrin rẹ yóo jí dìde.” Mata dá a lóhùn pé, “Mo mọ̀ pé yóo jí dìde ní ajinde ọjọ́ ìkẹyìn.” Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ajinde ati ìyè. Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, sibẹ yóo yè. Gbogbo ẹni tí ó bá wà láàyè, tí ó bá gbà mí gbọ́, kò ní kú laelae. Ǹjẹ́ o gba èyí gbọ́?” Ó dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, mo gbàgbọ́ pé ìwọ ni Mesaya Ọmọ Ọlọrun tí ó ń bọ̀ wá sí ayé.” Nígbà tí Mata ti sọ báyìí tán, ó lọ pe Maria arabinrin rẹ̀ sí ìkọ̀kọ̀. Ó ní, “Olùkọ́ni ti dé, ó ń pè ọ́.” Bí Maria ti gbọ́, ó dìde kíá, ó bá lọ sọ́dọ̀ Jesu. (Jesu kò tíì wọ ìlú, ó wà ní ibi tí Mata ti pàdé rẹ̀.) Nígbà tí àwọn Juu tí ó wà ninu ilé pẹlu Maria, tí wọn ń tù ú ninu, rí i pé ó sáré dìde, ó jáde, àwọn náà tẹ̀lé e, wọ́n ṣebí ó ń lọ sí ibojì láti lọ sunkún ni. Nígbà tí Maria dé ibi tí Jesu wà, bí ó ti rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú.” Nígbà tí Jesu rí i tí ó ń sunkún, tí àwọn Juu tí ó bá a jáde tún ń sunkún, orí rẹ̀ wú, ọkàn rẹ̀ wá bàjẹ́. Ó bi wọ́n pé, “Níbo ni ẹ tẹ́ ẹ sí?” Wọ́n sọ fún un pé, “Oluwa, wá wò ó.” Ni Jesu bá bú sẹ́kún. Nígbà náà ni àwọn Juu sọ pé, “Ẹ ò rí i bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!” Àwọn kan ninu wọn ń sọ pé, “Ọkunrin yìí tí ó la ojú afọ́jú, ǹjẹ́ kò lè ṣe é kí ọkunrin yìí má fi kú?” Orí Jesu tún wú, ó bá lọ síbi ibojì. Ninu ihò òkúta ni ibojì náà wà, òkúta sì wà ní ẹnu ọ̀nà rẹ̀. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.” Mata, arabinrin ẹni tí ó kú, sọ fún un pé, “Oluwa, ó ti ń rùn, nítorí ó ti di òkú ọjọ́ mẹrin!” Jesu wí fún un pé, “Ṣebí mo ti sọ fún ọ pé bí o bá gbàgbọ́ ìwọ yóo rí ògo Ọlọrun.” Wọ́n bá gbé òkúta náà kúrò. Jesu gbé ojú sókè, ó ní, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí ò ń gbọ́ tèmi. Mo mọ̀ pé nígbà gbogbo ni ò ń gbọ́ tèmi, ṣugbọn nítorí ti àwọn eniyan tí ó dúró yíká ni mo ṣe sọ èyí kí wọ́n lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni o rán mi níṣẹ́.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó kígbe sókè pé, “Lasaru, jáde wá!” Ẹni tí ó ti kú náà bá jáde pẹlu aṣọ òkú tí wọ́n fi wé e lọ́wọ́ ati lẹ́sẹ̀ ati ọ̀já tí wọ́n fi dì í lójú. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ tú aṣọ kúrò lára rẹ̀, kí ẹ jẹ́ kí ó máa lọ.” Ọpọlọpọ ninu àwọn Juu tí ó wá sọ́dọ̀ Maria gba Jesu gbọ́ nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣe. Ṣugbọn àwọn kan ninu wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisi, wọ́n lọ sọ ohun gbogbo tí Jesu ṣe.

Àwọn fídíò fún JOHANU 11:18-46