JOHANU 10:7-18

JOHANU 10:7-18 YCE

Jesu tún sọ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn aguntan. Olè ati ọlọ́ṣà ni gbogbo àwọn tí wọ́n ti wá ṣiwaju mi. Ṣugbọn àwọn aguntan kò gbọ́ ti wọn. Èmi ni ìlẹ̀kùn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀dọ̀ mi wọlé yóo rí ìgbàlà, yóo máa wọlé, yóo máa jáde, yóo sì máa rí oúnjẹ jẹ. Olè kì í wá lásán, àfi kí ó wá jalè, kí ó wá pa eniyan, kí ó sì wá ba nǹkan jẹ́. Èmi wá kí eniyan lè ní ìyè, kí wọn lè ní i lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. “Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-aguntan rere, mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan. Alágbàṣe tí kì í ṣe olùṣọ́-aguntan, tí kì í sìí ṣe olówó aguntan, bí ó bá rí ìkookò tí ń bọ̀, a fi àwọn aguntan sílẹ̀, a sálọ. Ìkookò a gbé ninu àwọn aguntan lọ, a sì tú wọn ká, nítorí alágbàṣe lásán ni, kò bìkítà fún àwọn aguntan. Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Mo mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi náà sì mọ̀ mí, gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi náà sì mọ Baba. Mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan. Mo tún ní àwọn aguntan mìíràn tí kò sí ninu agbo yìí. Mo níláti dà wọ́n wá. Wọn yóo gbọ́ ohùn mi. Wọn yóo wá di agbo kan lábẹ́ olùṣọ́-aguntan kan. “Ìdí rẹ̀ nìyí tí Baba fi fẹ́ràn mi nítorí mo ṣetán láti kú, kí n lè tún wà láàyè. Ẹnikẹ́ni kò gba ẹ̀mí mi, ṣugbọn èmi fúnra mi ni mo yọ̀ǹda rẹ̀. Mo ní àṣẹ láti yọ̀ǹda rẹ̀, mo ní àṣẹ láti tún gbà á pada. Àṣẹ yìí ni mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ Baba mi.”

Àwọn fídíò fún JOHANU 10:7-18

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú JOHANU 10:7-18