Ní àkókò òtútù-nini, ó tó àkókò Àjọ̀dún Ìyàsímímọ́ Tẹmpili tí wọn ń ṣe ní Jerusalẹmu, Jesu ń rìn kiri ní apá ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí wọn ń pè ní Ọ̀dẹ̀dẹ̀ Solomoni ninu Tẹmpili. Àwọn Juu bá pagbo yí i ká, wọ́n sọ fún un pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóo tó fi ọkàn wa balẹ̀? Bí ìwọ bá ni Mesaya, sọ fún wa pàtó.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo sọ fun yín, ẹ kò gbàgbọ́. Iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní orúkọ Baba mi ń jẹ́rìí mi, ṣugbọn ẹ kò gbàgbọ́, nítorí ẹ kò sí ninu àwọn aguntan mi. Àwọn aguntan mi a máa gbọ́ ohùn mi, mo mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tẹ̀lé mi. Mo fún wọn ní ìyè ainipẹkun, wọn kò lè kú mọ́ laelae, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè já wọn gbà mọ́ mi lọ́wọ́. Ohun tí Baba mi ti fún mi tóbi ju ohun gbogbo lọ. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè já a gbà mọ́ Baba mi lọ́wọ́. Ọ̀kan ni èmi ati Baba mi.” Àwọn Juu tún ṣa òkúta láti sọ lù ú. Jesu wá bi wọ́n pé, “Ọpọlọpọ iṣẹ́ rere ni mo ti fihàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba. Nítorí èwo ni ẹ fi fẹ́ sọ mí ní òkúta ninu wọn?”
Kà JOHANU 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOHANU 10:22-32
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò