Ní ọjọ́ keji, bí Johanu ati àwọn meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti tún dúró, ó tẹjú mọ́ Jesu bí ó ti ń kọjá lọ, ó ní, “Wo ọ̀dọ́ aguntan Ọlọrun.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn meji náà gbọ́, wọ́n tẹ̀lé Jesu. Nígbà tí Jesu yipada, tí ó rí wọn tí wọn ń tẹ̀lé òun, ó bi wọn pé, “Kí ni ẹ̀ ń wá?” Wọ́n ní, “Rabi, níbo ni ò ń gbé?” (Ìtumọ̀ “Rabi” ni “Olùkọ́ni.”) Ó ní, “Ẹ ká lọ, ẹ óo sì rí i.” Wọ́n bá bá a lọ, wọ́n rí ibi tí ó ń gbé. Wọ́n dúró lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí ó ti tó bí nǹkan agogo mẹrin ìrọ̀lẹ́.
Kà JOHANU 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOHANU 1:35-39
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò